Kí Ni Ète Mi? Kíkọ́ Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Àwọn ẸlòmírànÀpẹrẹ

Àṣẹ Méjì
Àfiyèsí
Ní òní, a óò gbé ète wa tí ó ga jù lọ yẹ̀ wò — láti ní ìfẹ́ Ọlọ́run àti ẹnìkejì wa. Wá àkókò díẹ̀ láti gba àdúrà, fi tọkàntọkàn sọ bí nǹkan ṣe rí ninu rẹ nípa apá yìí nínú ète ìgbésí ayé rẹ ní ìṣẹ́jú yìí.
Tẹ́ etí sílẹ̀
Ìyá wa, Térésà— Ẹ̀bùn fún Ọlọ́run
“Fi ara rẹ sí abẹ́ ìdarí Jésù pátápátá, kí ó lè ro èrò rẹ̀ nínú ọkàn rẹ, nítorí náà iṣẹ́ rẹ̀ nípasẹ̀ ọwọ́ rẹ, fún ọ yóò ní agbára lórí ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ láti fún ẹ ní okun.”
Howard Thurman — Jésù Àti Àwọn Tí Wọ́n Sọ Di Aláìní Ogún
“Gbogbo ènìyàn lè jẹ́ ẹnìkejì ẹlòmíràn. Àjọṣe àdúgbò kì í ṣe ti àyè; ó jẹ́ èyí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà rere. Ọkùnrin kan gbọ́dọ̀ fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ̀ ní tààràtà, ní kedere, láì sí àlàfo.”
Múu lò
Báwo ni ìgbésí ayé rẹ ṣe máa yí padà tàbí kí o yí i padà tí ó bá jẹ́ pé àwọn òfin méjì tí ó tóbi jù lọ ni Jésù fi sọ ohun tí ó o fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe? Báwo ni o ṣe lè yàn láti ní ìfẹ́ Ọlọ́run àti àwọn tí ó wà ní àyíká rẹ ní òní?
Dáhùn
Ní àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀, a óò ṣe ìwádìí ohun tí ó túmọ̀ sí láti ní ète tí ó dá l'órí níní ìfẹ́ Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run fi sí àyíká wa. Bí a ṣe ń parí àdúrà ìfọkànsìn ti òní, a pè ọ́ sí àdúrà ṣókí yìí:
“Olúwa, ṣí ọkàn mi, èmí mi, àti èrò inú mi láti ní ìfẹ́ rẹ àti ìfẹ́ ẹnìkejì mi.”
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ye ète rẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Jésù: láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn. Lórí awọn ọjọ méje, a yoo tu awọn àkórí ti ìjọsìn ti ara ẹni, ìyípadà, aanu, iṣẹ, ati ìdájọ. Ìpàdé kọ̀ọ̀kan máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà kan láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ni ìfòjúsùn sórí ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ náà, àyọkà kan tàbí méjì láti inú ìwé mímọ́, èrò kan láti inú ojú ìwòye ẹ̀kọ́ ìsìn, àti àwọn ọ̀nà láti fi sílò kí o sì dáhùn padà sí kíkà náà.
More