Kí Ni Ète Mi? Kíkọ́ Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Àwọn ẸlòmírànÀpẹrẹ

What Is My Purpose? Learning to Love God and Love Others

Ọjọ́ 5 nínú 7

Ìkáànú

Ìdojúkọ

Ìyípadà Ìfẹ́ ni Ọlọ́run ṣe pè wá sínú ìgbésí ayé ìfẹ́ — ọ̀kan ti o jẹ àmì àkọ́kọ́ nípasẹ̀ àánú.Kí o tó lọ si ìfọkànsìn tí ó kú yí, ló àkókò díẹ̀ láti wo ohun ti o jọ láti gbé ni àánú ṣíṣe.

Tẹ́tí sílẹ̀

Henri Nouwen—Àánú

"Àánú ń béèrè lọ́wọ́ wá láti lọ si ibi ti o ni ìpalára, láti wọ inú àwọn ìrora, láti pín nínú ìròbìnújẹ́, ìbẹ̀rù, ìpòrùúrú, àti ìpọ́njú. Àánú ń pè wá níjà láti kígbe pẹ̀lú àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú, láti ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó dáwà, láti sọkún pẹ̀lú àwọn tí ó wà nínú omijé.

Àánú nílò pé kí a jẹ aláìlera pẹ̀lú àwọn aláìlera, alàìlókun pẹ̀lú àwọn alàìlókun, àti aláìlágbára pẹ̀lú àwọn aláìlágbára. Àánú túmọ̀ sí ìrìbọmi ni kíkún ní ipò jíjẹ́ ènìyàn.”

Ẹ muló

Nípa ìdiwọ̀n tí Jésù, ète wa kì í ṣe nípa iye owó tí a lè ní lọ́wọ́, àwọn ohun ìní wá, ìtayọ ọ́lá wá láàrín àwọn ojúgbà wá, tàbí àṣeyọrí wá nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́. Ó jẹ ìwọ̀n ìyọ́nú tí ó ń ṣàn láti ọ̀dọ̀ wa tí ó sì ń tàn dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, láìka ẹnì kọ̀ọ̀kan, ipò, tàbí àyè tí a wà sì.

Kíní ìgbésí ayé rẹ yóò ti ri ti irú àánú yii ba wa pẹ̀lú rẹ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀?


Kíní yóò ṣe jẹ bakanna bí ó ti ri báyìí? Kíni yóò yàtọ̀ níbẹ̀?

Dáhùn sì

Bí o ṣe ń ronú lórí ìpè Kristẹni rẹ àti ète ìyọ́nú, gbàdúrà yìí:

Olúwa Ọlọ́run, Ó ṣeun fún àánú, oore-ọ̀fẹ́, àti àánú tí ó ti fi hàn mí. Fi Ẹ̀mí Rẹ̀ kún mi: ìfẹ́ rẹ, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù, inú rere, oore, òtítọ́, ìwà pẹ̀lẹ́, àti ìkóra-ẹni-níjaanú pẹ̀lú

Amin

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

What Is My Purpose? Learning to Love God and Love Others

Ye ète rẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Jésù: láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn. Lórí awọn ọjọ méje, a yoo tu awọn àkórí ti ìjọsìn ti ara ẹni, ìyípadà, aanu, iṣẹ, ati ìdájọ. Ìpàdé kọ̀ọ̀kan máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà kan láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ni ìfòjúsùn sórí ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ náà, àyọkà kan tàbí méjì láti inú ìwé mímọ́, èrò kan láti inú ojú ìwòye ẹ̀kọ́ ìsìn, àti àwọn ọ̀nà láti fi sílò kí o sì dáhùn padà sí kíkà náà.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọ́wọ́ TENx10 fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.tenx10.org/