Kí Ni Ète Mi? Kíkọ́ Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Àwọn ẸlòmírànÀpẹrẹ

Ìsìn
Àfiyèsí
Ọ̀kan lára ọ̀nà tó ga jù lọ tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa ni pé ká máa ṣe iṣẹ́ ìsìn. Ṣáájú kí o tó tẹ̀síwájú, lo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti ṣàṣàrò, kí o sì ronú nípa bí a ṣe lè pè ọ́ ní ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀, tí a sì dá ọ láti sin àwọn tó yí ọ ká.
Tẹ́tísílẹ̀
St. Teresa ti Avila — Kristi Kò Ní Ara
“Kristi kò ní ara àyàfi tìrẹ,
Kò sí ọwọ́, kò sí ẹsẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé àfi tìrẹ,
Ìwọ ni ojú tí ó fi ń wo
Ìyọ́nú nínú ayé yìí,
Àwọn ẹsẹ̀ rẹ ni ó fi ń rìn láti ṣe rere,
Ọwọ́ rẹ ni ó fi ń bù kún gbogbo ayé.”
Mátíù 25:34-36;40 (NLT)
“Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òǹgbẹ gbẹ mí, ẹ̀yin sì fún mi ní omi. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi, àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò.’ ...
‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin ṣe nǹkan wọ̀nyí fún àwọn arákùnrin mi yìí tí o kéré jú lọ, ẹ̀ ń ṣe wọn fún mi ni!’
Ìgbésẹ̀ Kẹ̀ta: Múulò (Ní ọ̀rọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí àádọ́ta)
Bá a ṣe ń bá àpèjúwe nípa jíjẹ́ ara Kristi lọ, lo àwọn ẹ̀yà ara tá a tò sísàlẹ̀ yìí láti ronú nípa bó o ṣe lè sin àwọn ẹlòmíràn:
Ọwọ́:
Ẹsẹ̀:
Ojú:
Etí:
Ẹnu:
Ọkàn:
Ọpọlọ
Ìgbésẹ̀ Kẹrin: Dáhùn (Ní ọ̀rọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí àádọ́ta)
Bó o ṣe ń parí àdúrà ìfọkànsìn yìí, ronú nípa ojú ìwòye tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó o ní, ohun tó o fi ṣe iṣẹ́ rẹ, ẹ̀bùn àbínibí rẹ, ìwà rẹ, ìrírí rẹ, àti ọ̀nà tá a lè gbà sin Ọlọ́run àti àwọn ẹlòmíràn.
Gbàdúrà sí Ọlọ́run láti ṣí ojú rẹ sí àwọn àǹfààní tuntun, etí rẹ sí àwọn ènìyàn tó yí ọ ká, àti ọkàn àti èrò rẹ sí àwọn àìní àwùjọ rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ye ète rẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Jésù: láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn. Lórí awọn ọjọ méje, a yoo tu awọn àkórí ti ìjọsìn ti ara ẹni, ìyípadà, aanu, iṣẹ, ati ìdájọ. Ìpàdé kọ̀ọ̀kan máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà kan láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ni ìfòjúsùn sórí ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ náà, àyọkà kan tàbí méjì láti inú ìwé mímọ́, èrò kan láti inú ojú ìwòye ẹ̀kọ́ ìsìn, àti àwọn ọ̀nà láti fi sílò kí o sì dáhùn padà sí kíkà náà.
More