Ìjọsìn fún Ọlọ́runÀpẹrẹ

Worshipping God

Ọjọ́ 6 nínú 6

Àwọn Ẹ́bún È̩mí àti Ìjọ́sìn

Nígbà tí a bá lo àwọn ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ àti onírúurú èdè nínú ìjọ, wọ́n máa ń yọrí sí ìyípadà. Nígbà tí Jésú ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, Á sọ pé, "Lọ sí ọ̀dọ̀ àlùfáà; jẹ́ kí ó rí ọ. Jẹ́ kí ó ríi pé o kìí ṣe adẹ́tẹ̀ mọ́." Kò sí ìdí kankan láti fọ́nnu tàbí díbọ́n.

Àwọn ẹ̀bùn ti È̩mí gidi yóò túmọ̀ sí pé iṣẹ́ ìyanu kò ní ìyèméjì nínú, àwọn ìmúláradá kò ní mú iyèméjì dání—àwọn ènìyàn á sì yí padà.

Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá ń lo àwọn ẹ̀bùn yìí, ní àìṣe àníàní, kìí ṣe gbogbo Krìstẹ́nì ni ó ní wọn. Gbogbo wa ni a ní ẹ̀bùn tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, gbogbo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fi ọwọ́ tọ́ wa ní èjìká tí ó sì fún wa ṣe pàtàkì bákan náà nínú ara. Nínú àgọ́ ara wa, tí a bá ní ọgbẹ́ ní ọmọ ìka ẹsẹ̀ kan, inú ìnira ni a máa wà ní gbogbo ọjọ́ yẹn. È̩yà ara tí ó kéré jù nínú ara lè ní ipa lórí gbogbo èyí tí ó kù.

Nígbà tí a bá dé ọ̀run, àyẹ́sí ti ibẹ̀ kò ní bá ti orí ilẹ̀ ayé mu. Ní ọ̀run, ẹni tí ó jẹ́ bí ọmọ ìka ẹsẹ̀ tí ó kéré jùlọ nínú ara yóò gba èrè tí ó tó ti ojú tí ó bá ti ṣe olótìítọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worshipping God

Ibi kíkà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ń fún wa ní ìṣírí nípa bí a ṣe lè sin Ọlọ́run ní gbogbo agbọn ayé wa, yíó sì tún ru àwọn òǹkàwé sókè láti d'arí ọkàn wọn sí ìbájọṣepọ̀ won pẹ̀lú Krístì. Ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí dá lé orí ìwé R. T. Kendall Worshipping God (Sínsin Ọlọ́run). (R. T. Kendall jẹ́ olùṣó-àgùntàn ilé-ìjọsìn Westminster ní ìlú London, England, fún bíi ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n.)

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ R. T. Kendall àti Charisma House fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò: http://bit.ly/kendallkindle