Ìjọsìn fún Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ìjọsìn Bíi Ìgbé Ayé
Nígbà tí mo wà nínú ẹgàwọn ọjọ́bẹ́ afi-ohun èlò orin kọrin kan, mo kọ́ ẹ̀kọ́ wípé nígbà tí adarí bá mú orin kan wá, ó fẹ́ kí enì kọ̀ọ̀kan nínú àwọn alu ohun èlò ṣe àgbéyẹ̀wò orin náà láàrin ọ̀sẹ̀ ni. Nítorí náà mo ní láti mú ìwé orin lo sí ilé pẹ̀lú ù mi. Bí àpapò ohunelo orin bá ṣe dún dáadáa sí nígbà ìpalẹ̀mọ́ dá lórí bí ẹni kọ̀ọ̀kan àwọn alu-ohun-èlò-orin ti ṣe bójú tó ipa tirẹ̀
Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe rí pẹ̀lú ìjọsìn. Tí a bá jẹ́ alágàgebè, tí ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ wa kò sì ní òtítọ́, tí a bá wá sí ilé ìjọsìn láti kọrin tí á sì sìn, ìjọ́sìn wa kò le múná d'óko àti wípé a kò ní kọ orin ní ọ̀nà tí yíò wu Ọlọ́run.
Ohun tí a jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi ẹnìkan, ní wákàtí mẹ́rìnlélógún ojúmó kan, ṣe pàtàkì ju ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní ilé ìjọsìn lẹ́ẹ̀kan l'ọ́ṣẹ̀ lọ. Àṣírí ìjọsìn tí ó ní ìtẹ́wọ́gbà wà nínú u bí a ṣe ń ṣe ní ilé tàbi ní ibi iṣẹ́ wa, àti ní ìgbà tí a bá dá wà tí kò sí eni tí ó mọ ohun tí à ń ṣe. Ó níí ṣe pẹ̀lú gbogbo ìgbésí ayé e wa.
Ọ̀nà tí a lè gbà láti má di alágàgebè ní ọjọ́ mẹ́fà nínú ọ̀sẹ̀ ni kí á máa lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ayé e wa. Kí á tó le ṣe èyí, a ní láti mú ìkorò kúrò nínú ayé wa. A gbọ́dọ̀ wá láti kún fún ìfẹ́ àti ìdáríjìn nítòótó àti kí á gba ọ̀kọ̀ọ̀kan ara wa bí a ṣe rí. A gbọ́dọ̀ gbé ìgbé ayé e ìfaraenijì, kí á máa wá láti nìkan fi ìfẹ́ hàn ní gbogbo ìgbà, kí á sì sin Ọlọ́run nínú ìwà mímọ́, ìrẹ̀lẹ̀, àti àdúrà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ibi kíkà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ń fún wa ní ìṣírí nípa bí a ṣe lè sin Ọlọ́run ní gbogbo agbọn ayé wa, yíó sì tún ru àwọn òǹkàwé sókè láti d'arí ọkàn wọn sí ìbájọṣepọ̀ won pẹ̀lú Krístì. Ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí dá lé orí ìwé R. T. Kendall Worshipping God (Sínsin Ọlọ́run). (R. T. Kendall jẹ́ olùṣó-àgùntàn ilé-ìjọsìn Westminster ní ìlú London, England, fún bíi ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n.)
More