Ìjọsìn fún Ọlọ́runÀpẹrẹ

Worshipping God

Ọjọ́ 4 nínú 6

Ìjọsìn pẹ̀lú Gbogbo Ara Ẹni

Nígbà tí a bá ń sọ nípa ìmísí ti Ẹ̀mí, à ń sọ ní ọ̀nà kan nípa àwọn èrò. Mo gbà pé èyí léwu gan-an, nítorí pé bí nǹkan ṣe rí ní ara ènìyàn lè mú kó ṣe àwọn nǹkan tí ó ṣe àjèjì.

Àwọn ènìyàn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kì í jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí kò tọ́, tí ẹ̀rí ọkàn wọn sì ń dà wọ́n láàmú, lè wá láti ṣe àtúnṣe sí ìwà òmùgọ̀ tí wọ́n hù nípa ṣíṣe ohun tí wọ́n rò wípé ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. Ẹnìkan lè máa rò pé òun ń rí ìdarí ti ẹ̀mí nígbà tí ó jẹ́ pé gbogbo ohun tí ó ń ṣe ni pé ó ń sa ipá ni ti ènìyàn láti ṣe àtúnṣe sí àṣìṣe tí ó ti ṣe s'ẹ́yìn. Bí a bá ṣe ìgbọràn sí ìdarí ti Ẹ̀mí, ó máa ń yọrí sí ìbàlẹ̀ ọkàn tí kò ní àfiwé.

Ó rọrùn láti rò pé ìmísí tí ó jà jú ní ti ọgbọ́n inú tàbí ti ọpọlọ àròjinlẹ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fẹ́ láti bá wa sọ ọ̀rọ̀, kì í kàn-án ṣe ni ti óye nìkan. Ọlọ́run fẹ́ láti bá gbogbo ẹ̀dá wa sọ̀rọ̀ - ìyẹn àwọn èrò ara wa, ìmọ̀ inú wa àti ọkàn wa.

Ìjọsìn tòótọ́ máa ń wáyé nígbà tí a kò bá bẹ̀rù láti sọ ohun tí ó wà ní ọkàn wa. Ìjọsìn ni láti mú wa dé ibi tí a ti lè jẹ́ olóòótọ́. A kò ní láti màa ṣe àtẹ̀mọ́ra bí nǹkan ṣe rí l'ára wa nígbà tí a bá wà nítòsí Jésù. Kò ní bá wa wí fún ṣísọ òtítọ́ wa. Kò túmọ̀ sí pé a tọ̀nà, ṣùgbọ́n bí a bá jẹ́ olóòótọ́, Ó lè ràn wá lọ́wọ́, kí Ó sì mú kí a rí ibi tí a ti ṣe àṣìṣe, àti láti kojú òtítọ́.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worshipping God

Ibi kíkà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ń fún wa ní ìṣírí nípa bí a ṣe lè sin Ọlọ́run ní gbogbo agbọn ayé wa, yíó sì tún ru àwọn òǹkàwé sókè láti d'arí ọkàn wọn sí ìbájọṣepọ̀ won pẹ̀lú Krístì. Ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí dá lé orí ìwé R. T. Kendall Worshipping God (Sínsin Ọlọ́run). (R. T. Kendall jẹ́ olùṣó-àgùntàn ilé-ìjọsìn Westminster ní ìlú London, England, fún bíi ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n.)

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ R. T. Kendall àti Charisma House fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú sí, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò: http://bit.ly/kendallkindle