Ìjọsìn fún Ọlọ́runÀpẹrẹ

Bí A Ti Ṣe Lè Ní Ìjọsìn Tí ó Wà Láàyè
A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Ọlọ́run kí Ó jẹ́ Òun fúnra rẹ̀ nínú wa. Èyí túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Ó jẹ́ Òun fúnra Rẹ̀ nínú àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. A kò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ lòdì sí bí àwọn ẹlòmíràn ṣe ńṣe ìjọsìn wọn.
Àmọ́ ìjọsìn tó jẹ́ ti àwọn tí ó ga láwùjọ tàbí èyí tí ó dà bíi eré amárayá, ìjọsìn tí í ṣe ti ìṣe ara tàbí èyí tí ó kàn rẹwà nìkan jẹ́ ìjọsìn àforúkọ jẹ́ lásán. Ní òde ó ní ìrísí ìjọsìn ṣùgbọ́n kò si otitọ nínú rẹ̀. Ohun tí à ń fẹ́ ní ijọsin tí ó wà láàyè. Àmọ́ báwo ni èyí ṣe ma ún wáyé?
Àwọn ilé ìjọsìn wa kò yẹ kó jẹ́ ibi tí àwọn tí kò ti di àtúnbí ń wá ní Ọjọ́ Àìkú nítorí pé wọ́n "fẹ́ràn bí a ti ún ìjọsìn." Àwọn ilé ìjọsìn wa gbọ́dọ̀ jẹ́ ibi tí àwọn tí kò tíì di àtúnbí kò ti ní ìtura nítorí pé Ẹ̀mí ni ó ṣe pàtàkì, ohun sì ni ó ṣíwájú. Ìlànà tó ń darí wa gbọ́dọ̀ jẹ́ ìgbọràn sí Ẹ̀mí—ibi yòówù kí ó darí wa sí.
Orin Dáfídì 37:4 ṣe pàtàkì fún gbogbo wa, ẹnikẹ́ni tí a báà jẹ́ tàbí ohunkohun ti a bá fẹ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá yọ̀ nínú Olúwa, àwọn kan lára ìlépa wa lè di ohun tí kò ní sí mọ́, tí àwọn èròńgbà tuntun á sì rọ́pò wọn. Nítorí náà, kò ní bá ọgbọ́n mu ká máa ronú pé ohun kan pàtó la fẹ́ kí ìjọsìn wa jẹ́. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé à ń yọ̀ nínú Olúwa, kí a sì ma wòye ohun tí Ọlọ́run Yóò orin Dáfídìṣe.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ibi kíkà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ń fún wa ní ìṣírí nípa bí a ṣe lè sin Ọlọ́run ní gbogbo agbọn ayé wa, yíó sì tún ru àwọn òǹkàwé sókè láti d'arí ọkàn wọn sí ìbájọṣepọ̀ won pẹ̀lú Krístì. Ẹ̀kọ́ ìfọkànsìn yìí dá lé orí ìwé R. T. Kendall Worshipping God (Sínsin Ọlọ́run). (R. T. Kendall jẹ́ olùṣó-àgùntàn ilé-ìjọsìn Westminster ní ìlú London, England, fún bíi ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n.)
More