Ọjọ́ FalentáìnìÀpẹrẹ

Valentine's Day

Ọjọ́ 3 nínú 3

ÌDÁKẸ́JẸ́

“Olúwa Ọlọ́run yín ní àárín yín,

Olódùmarè yóò gbà ẹ́ là;

Yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí rẹ,

Òun yóò fi ìfẹ́ Rẹ̀ mú ọ dákẹ́,

Òun yóò fi orin kíkọ yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí rẹ.”

- Sefanáyà 3:17 YCE

Òtítọ́ tí ó ní agbára ni ó kún inú ẹsẹ Ìwé-Mímọ́ yìí, tí ó wúlò fún wa ní ònìí àti ní ọjọ́ iwájú. Ní àárín ọjọ́ díẹ̀ tí ó kọjá, a ti wo bí Ọlọ́run ṣe ń fẹ́ l'áti fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn sí wa àti l'áti fà wá sún mọ́ ọkàn Rẹ̀. Ní òní à n wo díẹ̀ nínú àwọn òtítọ́ míràn tí ó ṣe aṣojú ọkàn Rẹ pẹ̀lú, l'áti inú ẹsẹ̀ Ìwé-Mímọ́ t'òkè. A lè wọ nkan ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí a wò gbolohun “Òun yóò fi ìfẹ́ Rẹ̀ mú ọ dákẹ́.”

Ohun yòówù kí o ti sọ tàbí ohun tí o ti ṣe sí ẹ̀yìn, ìdáríjì ní ó máa jẹ́ kí o lè máa bá ìgbésí ayé rẹ lọ. Àmọ́ ṣá o, fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, agbára tí wọ́n ní l'áti dáríji ara wọn tàbí àwọn ẹlòmíràn ni ohun tí ń dá wọn dúró, tí ń dí wọn l'ọ́wọ́, tí ó sì ń dè'nà ìtẹ̀síwájú wọn ní ìkẹyìn. Ní ìgbà tí a bá dáríji, Ọlọ́run máa ń gbàgbé. Ó pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́, Ó sì pinnu pé Òun kò ní rántí wọn mọ́.

Ọlọ́run Olódùmarè fẹ́ kí o sinmi nínú ìfẹ́ Rẹ̀, ṣùgbọ́n ṣé nǹkan kan wà tí ó ń dí ọ l'ọ́wọ́ l'áti gba ìfẹ́ yìí? Ṣé ọ̀tá náà máa ń fi àṣìṣe tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tí o ti ṣe s'ẹ́yìn dá ọ ní ẹ̀bi léraléra? Bíbélì sọ pé tí o bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí o sì tọrọ ìdáríjì, Ọlọ́run á dárí jì ẹ́. Olùfisùn lè gbìyànjú l'áti fi ẹ̀sùn kàn ọ, kí ó sì rán ọ l'étí àwọn ohun tí ó ti kọjá, ṣùgbọ́n Bàbá rẹ ọ̀run yàn l'áti fi aṣọ òrùlé ìfẹ́ Rẹ̀ yí ọ ká, kò sì s'ọ̀rọ̀ ní'pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àṣìṣe rẹ. Ìfẹ́ tí ó dà bí ìbòjú yìí máa ń bò ó mọ́lẹ̀ ó sì máa ń dá ààbò bò ó; ó pèsè ìpamọ́ l'ọ́wọ́ àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ́ ní àtijọ́. Gbólóhùn náà “Òun yóò fi ìfẹ́ Rẹ̀ mú ọ dákẹ́”tún lè túmọ̀ sí ‘Òun yóò sọ ọ́ di ọ̀tun, yóò sì tù ọ́ nínú.’

Jẹ́ kí ìpolongo òtítọ́ Rẹ̀ mú gbogbo ìbẹ̀rù kúrò. Tí o bá dúró tí o sì fi etí sílẹ̀, wà á gbọ́ Ọ bí Ó ti n “fi orin kíkọ yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí rẹ.” Ní òde òní, máa sinmi nínú ìmọ̀ pé Ó ní ifẹ̀ẹ́ rẹ, Ó sì ń wá ire rẹ!

Gba àdúrà pẹ̀lú mi:

Bàbá,

Mo dúpẹ́ pé ìfẹ́ Rẹ lè mú kí ara tù mí kí n sì wà ní ìdákẹ́jẹ́. Mo dúpẹ́ pé O mọ̀ mí, O kò sì ní àṣìṣe kankan tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan sí mi. Mo dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Yìn ní ọjọ́ òní, mo sì dúpẹ́ pé Ẹ pè mí ní ọmọ.

Ní orúkọ Jésù, àmín.

Fún àwọn ìfọkànsìn míràn l'áti CBN Europe, tàbí l'áti mọ púpọ̀ sí i nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, jọ̀wọ́ tẹ ibí.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Valentine's Day

Ọjọ́ Falentáìnì lè jẹ́ àkókò ẹ̀tàn fún díẹ̀ nínú wa. A lè wà ní ìpele kan tí a kò sí nínú ìdá ọ̀rẹ́ pẹ̀lú ẹnì kankan, ṣùgbọ́n tí ó wù wá pé kí á ní ọ̀rẹ́, èyí tí ó lè má rọrùn fún wa. Ní ọjọ́ mẹ́ta tí ó ńbọ̀ yìí, láì bìkítà ipò ìbátan rẹ, jẹ́ kí á gba ọkàn rẹ ní ìyànjú pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run ALÁRINRIN, ALÁÌNÍ ÌTORÍ, ÌDÁKẸ́JẸ́.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọwọ́ CBN Europe fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí iwájú síi, ṣe àbẹ̀wò: https://www.cbneurope.com/yv