Ọjọ́ FalentáìnìÀpẹrẹ

LÁÌ NÍ ÌTORÍ
“….Ìfẹ́ àìlópin ni mo ní sí ọ, nítorí náà n kò ní yé máa fi òtítọ́ bá ọ lò.”
- Jeremaya 31:3 YCE
Ní ònìí, àti ní ọjọ́ gbogbo, Bàbá Ọ̀run kan ní ìfẹ́ rẹ láì tẹ̀tì. Ìfẹ́ Rẹ̀ kò ní òpin ó sì wà títí láéláé. Olódodo ni títí, inú rere Rẹ̀ tí kìí kùnà ni a rí nínú àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe Rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ jẹ́ ìfihàn ìfẹ́ àti àánú tí ó wà nínú ọkàn Rẹ̀, ó sì ń fi hàn fún àwọn ọmọ Rẹ̀ ní ìgbà gbogbo. Ọ́ mọ̀ ọ́ kí a tó ní oyún rẹ. Kí o tó mí èémí rẹ àkọ́kọ́, Ó yàn l'áti fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn sí ọ ní àì ní òdiwọ̀n Ó sì tún ń ṣe é síbẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ònfà méjì tí ojú ìfàá wọn wà papọ̀, agbára ònfà á fa àwọn méjèèjì pọ̀, yoó sì nira l'áti pín wọn níyà. Ní ìgbà tí a bá súnmọ́ ọn tí a sì jẹ́ kí ọkàn wa wà ní gbangba kedere ní iwájú Rẹ̀, ìfẹ́ẹ Rẹ̀ yó sun yó sí gbogbo ibi kọ́lọ́fín ayé wa, yíò sì lé gbogbo ẹ̀dùn ọkàn àti ẹ̀rù jáde.
Kò sí ohun tí a lè fi rọ́pò ìfihàn ìfẹ́ òtítọ́ tí Bàbá Ọ̀run ní sí wa. Kí á ní ìfẹ́ wa nítòótọ́ kí á sì jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà jẹ́ àfẹ́rí ọkàn àti àfojúsùn gbogbo wa. Kí Bàbá tí kò ní àbùkù kankan, tí ó wà fún wa tí kò sì lòdì sí wa ní ìfẹ́ wa, kí ó sì mọ̀ wá jẹ́ ohun tí ó dára jù lọ. Ó fẹ́ kí á mọ Òun kí á sì rìn ní ọ̀nà Rẹ̀.
Gba àdúrà yìí pẹ̀lú mi:
Bàbá,
Mo dúpẹ́ nítorí pé O ti fẹ́ mi pẹ̀lú ìfẹ́ ayéraye. Kí n tílẹ̀ tó mí èémí mi àkọ́kọ́, O ti mọ̀ mí, ojoojúmọ́ ni O sì ń fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn sí mi ní àì ní òdiwọ̀n. Jẹ́ kí gbogbo lílù ọkàn mi wà ní ìbámu pẹ̀lú Rẹ. Máa fà mí súnmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ ní ìgbà gbogbo kí n lè mọ àwọn ọ̀nà Rẹ. Kọ́ mi l'áti ní ìfẹ́ àwọn ẹlòmíràn bí O ti ní ìfẹ́ mi, sì jẹ́ kí ayé mi jẹ́ àfihàn oore àti àánú Rẹ nínú àwọn ìṣe àti ọ̀rọ̀ mi.
Ní orúkọ́ Jésù, àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọjọ́ Falentáìnì lè jẹ́ àkókò ẹ̀tàn fún díẹ̀ nínú wa. A lè wà ní ìpele kan tí a kò sí nínú ìdá ọ̀rẹ́ pẹ̀lú ẹnì kankan, ṣùgbọ́n tí ó wù wá pé kí á ní ọ̀rẹ́, èyí tí ó lè má rọrùn fún wa. Ní ọjọ́ mẹ́ta tí ó ńbọ̀ yìí, láì bìkítà ipò ìbátan rẹ, jẹ́ kí á gba ọkàn rẹ ní ìyànjú pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run ALÁRINRIN, ALÁÌNÍ ÌTORÍ, ÌDÁKẸ́JẸ́.
More