Ọjọ́ FalentáìnìÀpẹrẹ

ALÁRINRIN
“Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba fi fẹ́ wa, tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọ́run; bẹ́ẹ̀ ni a sá à jẹ́!”
- 1 Jòhánù 3:1
Yálà o mọ̀ ọ́ tàbí o ní oye rẹ̀ ní kíkún, òtítọ́ ni pé Ọlọ́run – Ẹlẹ́dàá àgbáyé – ní ìfẹ̀ẹ́ èmi àti ìwọ láì sí ààlà. Ojoojúmọ́ ni ó máa ń yàn láti fi ìfẹ́ ńláǹlà rẹ̀ hàn sí wa. Ojoojúmọ́, Ó fẹ́ kí ọkàn wa ṣí sílẹ̀ láti ní oye ìtóbi àti ìtóbi ìfẹ́ rẹ̀ sí wa. Pé a lè mọ ìbú àti gígùn, gíga àti ìjìnlẹ̀, àti ìtóbi ìfẹ́ ìyanu rẹ̀ sí wa ni ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wa. Láti ní ìrírí ìfẹ́ Bàbá pípé tí ó ṣe ìlérí,“Èmi kì yóò fi ọ́ [nínú ipò èyíkéyìí] láé [tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ tàbí fi ọ́ sílẹ̀ láìní ìtìlẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà lọ́nàkọnà], bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ tàbí já ọ kulẹ̀ tàbí jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ [ní tòótọ́ Èmi kì yíò fi ó sílẹ̀]!”- Ìwé Hébérù 13:5 AMP
Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kìí ṣe àwọn ìlérí òfo. Wọ́n jẹ́ òtítọ́. Wọ́n jẹ́ ìfihàn Bàbá Ọ̀run kan tí ó ní ìfẹ̀ẹ́ tí ó sì ń fẹ́ ohun tí ó dára jùlọ fún àwọn ọmọ Rẹ̀. Ìfẹ́ Rẹ nbẹ ní ọkàn Rẹ sí wa; Ó ńfẹ́ kí á lè mọ̀ kí á sì ní ìrírí rẹ nínú ayé wa.
Ní òní, gba àdúrà ránpẹ́ yìí pẹ̀lú mi:
Bàbá,
Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé, ní ojoojúmọ́, ìwọ fi ìfẹ́ rẹ hàn sí mi, o sì ní ìfẹ́ mi láì ní òdiwọ̀n. Mo mọ oore fún gbogbo ìgbà. O ṣeun fún òtítọ́ ọ̀rọ̀ rẹ pé ìwọ kì yóò fi mí sílẹ̀ tàbí kọ̀ mí sílẹ̀. O ṣe ìlérí pé ìwọ kì yóò jẹ́ kí n ṣubú tàbí sinmi láti dì mí mú. Jẹ́ kí n sinmi nínú ìmọ̀ pé ìwọ ni Baba pípé tí ó ní ire mi ní ọkàn. Ràn mí lọ́wọ́ láti mọ̀ àti ní òye títóbi ìfẹ́ rẹ. O ṣeun pé mo lè ní ìdánilójú pé ìwọ ni Baba mi àti pé ọjọ́ iwájú mi wà ní àìléwu ní ọwọ́ rẹ.
Ní orúkọ Jésù, àmín
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọjọ́ Falentáìnì lè jẹ́ àkókò ẹ̀tàn fún díẹ̀ nínú wa. A lè wà ní ìpele kan tí a kò sí nínú ìdá ọ̀rẹ́ pẹ̀lú ẹnì kankan, ṣùgbọ́n tí ó wù wá pé kí á ní ọ̀rẹ́, èyí tí ó lè má rọrùn fún wa. Ní ọjọ́ mẹ́ta tí ó ńbọ̀ yìí, láì bìkítà ipò ìbátan rẹ, jẹ́ kí á gba ọkàn rẹ ní ìyànjú pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run ALÁRINRIN, ALÁÌNÍ ÌTORÍ, ÌDÁKẸ́JẸ́.
More