Gbígbé nínú Jésù - Ètò-ẹ̀kọ́ Ìfọkànsìn Ọlọ́jọ́ Mẹ́rin lórí Ìwásáyé JésùÀpẹrẹ

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò tó dára jù lọ nínú ọdún nìyí, gẹ́gẹ́ bí orin kan ṣe sọ, a ṣì nílò àdúrà - bóyá láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìbùkún Rẹ̀ tàbí ká kàn béèrè fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ láti kojú másùn máwo tàbí àwọn ìṣòro tí àkókò ọdún lè mú wá. Àdúrà máa ń jẹ́ kí ọkàn wa mọ̀ pé Ọlọ́run wà nítòsí wa, pé Ó jẹ́ adúróṣinṣin àti ibi ìsádi.
Àmọ́, ǹjẹ́ o ti rí i rí pé o ò mọ ohun tó yẹ kó o gbàdúrà nípa? Ó lè jẹ́ pé àdúrà rẹ ti di èyí tí kò nítumọ̀ tàbí pé o ti ń gbàdúrà léraléra, ó sì lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ọ̀nà tí ò tọ́ lo gbà ń gbàdúrà? Ìgbẹ́kẹ̀lé tí o ní nínú àdúrà rẹ yóò túbọ̀ lágbára sí i nígbà tí o bá ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba àdúrà rẹ.
Àdúrà pọ̀ nínú Bíbélì! Láti Jẹ́nẹ́sísì títí dé Ìṣípayá, a rí àwọn àdúrà tí á lè yá láti mú kí ìgbésí ayé wa nípa tẹ̀mí túbọ̀ lágbára sí i. Àwọn àdúrà yìí máa ń jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa àti ohun tí ńṣe wá - wo ìwé Sáàmù!
Bí a ṣe ń ka àwọn ìtàn, àrọ́bá, ewì, àti òwe inú Bíbélì ní iwájú Ọlọ́run tí á sì kíyèsí Ẹ̀mí, a ó máa rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí ó kan ìgbésí ayé wa, ayé tí á ń gbé àti àwọn ènìyàn tí á mọ̀. Bí àkókò ti ń lọ, yóò di ìṣe gbogbo ìgbà láti máa sọ àwọn èrò wọ̀nyí di àdúrà lójú ẹsẹ̀.
Ka Lúùkù 2:8-18. Báwo ni o ṣe gbọ́ ìhìn rere àti ìrírí rẹ̀ nípa Jésù? Nínú ìtàn yìí, áńgẹ́lì kan wá sọ́dọ̀ àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ń ṣiṣẹ́ kára ó sì kéde pé ohun pàtàkì kan ṣẹlẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù (v. 11). Torí náà, àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà lọ sí Ìlú Dáfídì, níbi tí wọ́n ti rí Jésù, Màríà àti Jósẹ́fù. Nígbà tí wọ́n rí ọmọ náà, wọ́n lọ káàkiri, wọ́n sì sọ fún gbogbo àwọn tí wọ́n mọ̀ nípa ìbí Jésù àti ohun tí àwọn áńgẹ́lì sọ nípa Rẹ̀ (vv. 17-18).
Báwo ni o ṣe lè ṣe bíi ti àwọn olùṣọ́ àgùntàn, kí o máa sọ nípa Jésù fún gbogbo ènìyàn, pàápàá lákòókò ọdún yìí? Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ṣiṣẹ́ nínú ọkàn àwọn tí o mọ̀. Máa fetí sílẹ̀ dáadáa, kí o sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tí o dáa dípò tí wàá fi máa dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́. Máa fì hìn rere náà hàn nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn, kì í ṣe ọ̀rọ̀ lásán ni kérésìmesì yìí. Gbàdúrà pé kí ọ̀nà tí ó gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ àti àjọṣe tí ó ní pẹ̀lú àwọn ènìyàn lè mú kí wọ́n súnmọ́ Jésù.
Láti mọ sí i nípa àṣà ẹ̀mí fífi Ìwé Mímọ́ gbàdúrà àti àwọn àṣà míràn tí a mẹ́nu kàn nínú ètò ẹ̀kọ́ kíkà yìí, wo Abide Bible Journals láti ọwọ́ Thomas Nelson .
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Kérésìmesì ńbọ̀! Ó wá pẹ̀lú Ìwásáyé Jésù - ìmúrasílẹ̀ àti àjoyọ̀ ìbí Jésù. Sùgbọ́n njẹ́ ìmọ̀ yí kò ti sọnù nípasẹ̀ ìmúra ìsinmi ọdún, ríra ẹ̀bùn fún ọdún, tàbí ìgbàlejò àwọn ebí? Nínú lílọ sókè sódò àsìkò ọdún kérésìmesì, ní ìrírí titun nípa oríṣi ọ̀nà tí a lẹ gbà latí máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí yíò sì fà ó súnmọ́ Ọlọ́run. Jí ọkàn rẹ dìde nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí láti inú àwọn àkójọ Bíbélì Gbé-Inú láti ọwọ́ Thomas Nelson.
More