Gbígbé nínú Jésù - Ètò-ẹ̀kọ́ Ìfọkànsìn Ọlọ́jọ́ Mẹ́rin lórí Ìwásáyé JésùÀpẹrẹ

Abide in Jesus - 4-Day Advent Devotional

Ọjọ́ 2 nínú 4

Lọ́dọọdún kàlẹ́ndà àjọṣepọ̀ wà máa ń kún kíákíá ní àsìkò yìí nínú ọdún. Àwọn ayẹyẹ ọdún Kérésìmesì pẹlú àwọn ọ̀rẹ́, àpéjọ ẹbí, àwọn ojúṣe tí iṣẹ́, àwọn ètò ilé ìjọsìn - má sì gbàgbé gbogbo oúnjẹ sísè àti ìṣẹ́ ìmọ́tótó àti ọjà rírà àti iṣẹ́ ọ̀ṣọ́ tó máa ń wáyé. Gbogbo ìgbà la máa ń ṣí kiri ká, èyí sì máa ń mú kó ṣòro fún wà láti jí nípa tí ẹ̀mí.

Ní àkókò Kérésìmesì yìí - ó yẹ ki á dàbí màlúù. 

Ẹ dúró ná... màlúù?!?

Ronú nípa rẹ́ - àwọn màlúù máa ń tún oúnjẹ tí wọ́n ti gbémì jẹ. Àwọn màlúù nílò àwọn èròjà oúnjẹ kí wọ́n lè wà láàyè, nítorí náà wọ́n fi sùúrù rọra jẹ oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ, dípò tí wọ́n ì bá fi máa lọ́ koríko mì. Bákan náà ni, kàkàkí a fi máa lọ́ oúnjẹ ti ẹ̀mí ní ojoojúmọ́, a gbọ́dọ̀ máa fi ara balẹ̀ múu, kí á máa "jẹ" Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run léraléra jálẹ̀ ọjọ́. Èyí ní ohun tí àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì pé níṣíṣe àṣàrò. Ọ̀rọ̀ míràn fún èyí ni àròjinlẹ̀. 

Ohun tó yẹ kí á máa fi ṣe àfojúsùn wa ni pé kí a lè sinmi lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Fífetí sí ohùn Rẹ̀ dípò sísọ̀rọ̀. Dúró ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti ìsimi, pàápàá ní àkókò yíì, gbà ìgbìyànjú. Ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni oúnjẹ tí ọkàn wa nílò gidigidi láti wà láàyè. Bí o bá ṣe jókòó pẹ̀lú òtítọ́ Rẹ̀, tí o sì ń jẹ́ kí ó “silẹ̀” nínú ọkàn rẹ, ìwọ yóò túbọ̀ mọ̀ nípa wíwà tí Ọlọ́run wà nínú ìgbésí ayé rẹ àti ní àyíká rẹ. 

Kàá Matthew 1:22-25 lẹ́ẹ̀mejì. Wá ọ̀rọ̀ kàn tàbí gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí o tàn sí ọ̀.

Lẹ́yìn náà, ronú nípa ohun kan tí o kọgun sí ọ tí o lè fi wé ọ̀rọ̀ náà tàbí gbólóhùn tí o yàn. Kíni ìdí tí o fi yan ọ̀rọ̀ yìí, àti pé báwo ló sì ṣe kan ìgbésí ayé rẹ? Kíni ìdí tí ọ̀rọ̀ náà ṣe ní ìtumọ̀ sí ọ ní àkókò yìí?

Gbàdúrà, kí o sí béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti sọ ohun tí Ó fẹ́ sọ fún ọ ni kedere. Gbàdúrà pẹlú ìfojúsọ́nà kí o sì fi sùúrù dúró de ìdáhùn Rẹ̀.

Nìparí, fetí sílẹ̀ bí o bá ti jókòó pẹlú Ẹ̀mí Ọlọ́run. Padà sí ọ̀rọ̀ náà nígbà tí o bá yá. Njẹ́ Ọlọ́run tí fi ohun kan míràn hàn sí ọ́ bí o n ṣe ronú síwájú síi?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Abide in Jesus - 4-Day Advent Devotional

Kérésìmesì ńbọ̀! Ó wá pẹ̀lú Ìwásáyé Jésù - ìmúrasílẹ̀ àti àjoyọ̀ ìbí Jésù. Sùgbọ́n njẹ́ ìmọ̀ yí kò ti sọnù nípasẹ̀ ìmúra ìsinmi ọdún, ríra ẹ̀bùn fún ọdún, tàbí ìgbàlejò àwọn ebí? Nínú lílọ sókè sódò àsìkò ọdún kérésìmesì, ní ìrírí titun nípa oríṣi ọ̀nà tí a lẹ gbà latí máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí yíò sì fà ó súnmọ́ Ọlọ́run. Jí ọkàn rẹ dìde nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí láti inú àwọn àkójọ Bíbélì Gbé-Inú láti ọwọ́ Thomas Nelson.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ HarperCollins/Zondervan/Thomas Nelson fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.thomasnelsonbibles.com/abide-bible-journals/