Gbígbé nínú Jésù - Ètò-ẹ̀kọ́ Ìfọkànsìn Ọlọ́jọ́ Mẹ́rin lórí Ìwásáyé JésùÀpẹrẹ

Abide in Jesus - 4-Day Advent Devotional

Ọjọ́ 1 nínú 4

Kérésìmesì ti dé! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò ayọ̀ ni tí àwọn Kristẹni fi ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù, síbẹ̀ ó lè jẹ́ àkókò tí wàhálà, àníyàn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbòkègbodò máa ń bò wá mọ́lẹ̀ débi pé yóò palẹ̀ ohun ti ẹ̀mí kúrò lọ́kàn wa. Báwo ni a ṣe lè mú ọkàn wa tají, kí ẹ̀mí wà lákòókò Ọdún iwásáyé Jésù?

Ọ̀nà kan tí a lè gbà "wà ní ìmúra-sílè," gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ nínú àkàwé rẹ̀ tó wà nínú Máàkù 13, ni pé kí á máa ṣe àkọsílẹ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa.

Àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tí a ń kà máa jẹ́ kíá lè ronú jinlẹ̀ lórí ohun ti à ń kà, kì í wulẹ̀ ṣe pé a fẹ́ lóye ohun tá a kà nìkan, àmọ́ ó tún máa jẹ́ kí ohun tá à ń kà wọ̀ wá lọ́kàn. Àkọsílẹ̀ Bíbélì kò yàtò sí bí kí á bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ láì fì ohunkohun bò, àti pẹ̀lú òtítọ́. A lè gbógun ti iyèméjì àti ìbẹ̀rù wa, kí á sì gba itoni Ọlọ́run, kí á sì mọ ìwà àti ìṣe tí ó yẹ ká yí padà. Kò sí ọ̀nà tó dáa tàbí ọ̀nà tí kò dára láti kọ ìwé àkọsílẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni.

Gbìyànjú èyí: ṣí Bíbélì rẹ sí Máàkù 13:32-37, ṣùgbọ́n má ì tíì káà. Lákọkọ́, síi pẹ̀lú àdúrà, bèèrè pé kí Ọlọ́run bá o sọ̀rọ̀ àti pé kí Ó fi ara Rẹ hàn ọ́ nípasẹ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Gbàdúrà fún ọkàn tí ó ṣí àti ìyára sí gbogbo ohun tí Ó bá fẹ́ sọ fún o. Ní báyìí ka àyọkà láti inú ìwé Máàkù. Lákòtán, pẹ̀lú ìwé tí o fi ń ṣe àṣàrò, rò kí o sì kọ nípa àwọn ibeere tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí tí ó níí ṣe pẹ̀lú àyọkà náà:

  • Kí nìdí tí Jésù fi pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: "Ẹ máa ṣọ́ra! Ẹ wà lójúfò!" (v. 33)? Báwo ni o ṣe ń tẹ̀lé àṣẹ yìí?
  • Báwo ni o ṣe ń fi ìtára dúró de ìpadàbọ̀ Jésù? Báwo ni o ṣe ń pinu láti ronú nípa rẹ̀ tó ní gbogbo ìgbà tí ó kún fún ìgbòkègbodò? Kíni o lè ṣe láti túbọ̀ máa ṣọ́nà ní àkókò Kérésìmesì yìí?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Abide in Jesus - 4-Day Advent Devotional

Kérésìmesì ńbọ̀! Ó wá pẹ̀lú Ìwásáyé Jésù - ìmúrasílẹ̀ àti àjoyọ̀ ìbí Jésù. Sùgbọ́n njẹ́ ìmọ̀ yí kò ti sọnù nípasẹ̀ ìmúra ìsinmi ọdún, ríra ẹ̀bùn fún ọdún, tàbí ìgbàlejò àwọn ebí? Nínú lílọ sókè sódò àsìkò ọdún kérésìmesì, ní ìrírí titun nípa oríṣi ọ̀nà tí a lẹ gbà latí máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí yíò sì fà ó súnmọ́ Ọlọ́run. Jí ọkàn rẹ dìde nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí láti inú àwọn àkójọ Bíbélì Gbé-Inú láti ọwọ́ Thomas Nelson.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ HarperCollins/Zondervan/Thomas Nelson fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.thomasnelsonbibles.com/abide-bible-journals/