Gbígbé nínú Jésù - Ètò-ẹ̀kọ́ Ìfọkànsìn Ọlọ́jọ́ Mẹ́rin lórí Ìwásáyé JésùÀpẹrẹ

Abide in Jesus - 4-Day Advent Devotional

Ọjọ́ 3 nínú 4

Àkókò yìí nínú ọdún lè mú ká máa ronú nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o lè rántí ẹ̀bùn Kérésìmesì tó wù ẹ́ jù lọ tí o ti rí gbà rí? 

Tó bá rí bẹ́ẹ̀, tún ronú nípa ìrírí yẹn lẹ́ẹ̀kan síi. Àwọn ìró tàbí òórùn wo lo rántí ní àkókò yẹn? Ṣé o rántí bí ìwé tí wọ́n fi pọ́n ẹ̀bùn náà ṣe rí ní ọwọ́ rẹ àti bí o ṣe ń fa ìwé náà ya? Àwọ̀ wo ni ìwé náà? Ta ló wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ? Lílọ padà sínú ìrántí ìrírí yẹn pẹ̀lú irúfẹ́ ìmọnúúrò rẹ lágbára ó sì ṣeé ṣe kí ó mú àwọn ìmọ̀lára ìgbà yẹn padà wá. 

Nísinsìnyí, tí ó bá ń ka Ìwé Mímọ́ lọ́nà kan náà ńkọ́? A gbà pé o kò sí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì kankan; bíótiwù kó rí, tí o bá lo ìwòye inú rẹ tí ó sì rí ara rẹ bíi ọ̀kan nínú àwọn tí ó wà nínú Ìwé Mímọ́ ńkọ́?

Tí a bá tọ Bíbélì wá nípasẹ̀ ohun tí a rí, tí a gbọ́ ọ, tí a gbóòórùn, tí a tọ́ wò, tí a sì ń fọwọ́ kàn ó máa ń ṣèrànwọ́ gan-an fún àwọn tí wọ́n fẹ́ láti mọ̀ síi nípa ìwé mímọ́ pẹ̀lú ọgbọ́n orí, ní pàtàkì ní àkókò Ìwásáyé Jésù. Dípò tí aó fi máa wo òkodoro òtítọ́ látòkèèrè, a sún mọ́ ọ. Lílo àwọn eyà iwòye márùn-ún wa ń fún wa ní àǹfààní kí á lè lo agbára ìrònú tí Ọlọ́run fún wa nípa fífi ara wa sínú àwọn ìtàn inú ìwé mímọ́. Bí a ṣe ń bá àwọn èèyàn inú Bíbélì kẹ́dùn, a máa ń lóye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọn ní ọnà tó jẹ́ pé ìrírí ni a fi ń mọ̀ wọ́n. A kì í kàn kàwé lásán mọ́; a ó fi ara wa sí inú ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, jí ọkàn wa pépé.

O lè ka Mátíù 1:18-21 nínú Bíbélì rẹ. Kí ó tó kà á, mú ọkàn rẹ wá sí ìdákẹ́ jẹ kí o sì bẹ Ọlọ́run pé Kí Ó múra ọkàn rẹ sílẹ̀ Kí Ó sì darí ìrònú rẹ. Leyin èyí ka ẹsẹ náà.

Fi ojú inú wo bí Jósẹ́fù ṣe sùn lọ fọnfọn. Ayé dákẹ́, Ìwà tútù sì wà nínú afẹ́fẹ́. Fi ojú inú wo bí ó ṣe máa ya Jósẹ́fù lẹ́nu tó nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà ṣàdédé fara hàn án. Ǹjẹ́ ó pariwo fún ìyàlẹ́nu? Ǹjẹ́ ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, tí o sì yí ìdúró rẹ̀ pa dà? Kíni ó ńrò ní ọ́kàn rẹ̀ nígbà tí o gbọ́ pé Olùgbàlà tí áwọn ènìyàn òun ti ń retí tipẹ́tipẹ́ ń bọ̀? Ó dájú pé Jósẹ́fù gbà gbọ́ pé Ọlọ́run Yóò mú àwọn ìlérí Rẹ̀ ṣẹ. Ṣé ìwọ náà gbàgbọ́?

Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí o ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé àti òye tí Jósẹ́fù ní nígbà tí ańgẹ́lì Olúwa wá bẹ̀ ẹ́ wò. Bèrè kí Ọlọ́run fi àwọn ibi tí Ó ti lè lò ọ hàn láti ṣe iṣẹ́ rere fún ìjọba Rẹ̀.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Abide in Jesus - 4-Day Advent Devotional

Kérésìmesì ńbọ̀! Ó wá pẹ̀lú Ìwásáyé Jésù - ìmúrasílẹ̀ àti àjoyọ̀ ìbí Jésù. Sùgbọ́n njẹ́ ìmọ̀ yí kò ti sọnù nípasẹ̀ ìmúra ìsinmi ọdún, ríra ẹ̀bùn fún ọdún, tàbí ìgbàlejò àwọn ebí? Nínú lílọ sókè sódò àsìkò ọdún kérésìmesì, ní ìrírí titun nípa oríṣi ọ̀nà tí a lẹ gbà latí máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí yíò sì fà ó súnmọ́ Ọlọ́run. Jí ọkàn rẹ dìde nínú ètò ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí láti inú àwọn àkójọ Bíbélì Gbé-Inú láti ọwọ́ Thomas Nelson.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ HarperCollins/Zondervan/Thomas Nelson fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò sí: https://www.thomasnelsonbibles.com/abide-bible-journals/