Gbígbọ́ lati Ọ̀run: Títẹ́ Etí S'ílẹ̀ Sí Olúwa Nínú Ìgbésí Ayé Ojoojúmọ́Àpẹrẹ

Hearing From Heaven: Listening for the Lord in Daily Life

Ọjọ́ 5 nínú 5

Ohùn Ọ̀run Sọ Wípé, “Ẹ Sá Àsálà nínú Mi.”

Mo jè ẹni tí kò ní omi l'ara ní ìgbá tí mò ń dàgba. Ó sì ṣ'eni láàánú pé bákannáà ní ọ̀rọ̀ rí síbẹ̀.

Ìgbésí ayé ní inú ìgbèríko Nairobi kún fún ìjàkadì, àìlómilára mí ṣí mi sílẹ̀ sí ìwà ipá yi. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, yíò dàbi i k'ólóri-o-d'ori rẹ̀ mú ni. Àwọn òbí wa kò ni àkókó láti ri dájú wípé a kò kó si ọwọ́ apániláyà -- wọ́n ni láti sá eré iṣẹ òòjọ́ tí ó péye.

Ní ígbà tí mo wà ní kíláàsì kẹfà, mo ní ìrírí ìdààmú apániláyà tí ó burú jáì kán. Olórí wọn dàbí òmìrán! Ó d'ojutì mi. Ní opin ọ̀sẹ̀, mo rí ara mi nínú ìbànújẹ ọkàn. Sùgbọ́n mo lọ sí Ibùdó Àánú ni ilé ìjọsìn mi, ní ibi tí wọ́n ti s'ọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run tí o jẹ ààbò fún wa. Bí mo ṣe n gbọ́ ẹ̀kọ́ yìí, ìfẹ́ Olúwa tú jáde sí mi, ọkàn òtòṣì mi sì rí ìtùnú.

Ibùdó Àánu jẹ́ ìbí kán tí mo ti lè ní ìrírí ifọkanbalẹ àti ààbò. Àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ ṣe ìtọjú wa dáadáa wọ́n sì tù wá nínú.

Njẹ́ ẹ̀rù ti bà ọ́ rí? Njẹ́ o ti wà nínú ewu rí? Njẹ́ o ti jọ bí ẹni pé o kò ní agbára láti t'ọjú ẹ̀mí ara rẹ rí bí? A lè mú ìbẹ̀rù wa tọ Ọlọ́run wa lọ, nítorí pé Ọlọ́run rere ni. Ó ń gbọ́ igbe wa fún ààbò. Ó ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ ibi.

Gẹ́gẹ́ bí Dáfídì, o lè ké pe Ọlọ́run. Ó lè pa ẹ̀mí rẹ mọ́! Ó lè dáàbò bò ọ lọ́wọ́ àwọn ewu ayé yìí. Lo àkókò díẹ̀ kí o gba àdúrà fún gbogbo àwọn ọmọdé ní àgbáyé ti wọ́n ní ìpayà. Bẹ ẹ̀bẹ̀ àdúrà fún ẹ̀mí àti ọkàn wọn, béèrè wípé kí Olúwa fi ara Rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ìbí ààbò fún wọn. Àmín.

Kọ́ ẹkọ síwájú nípa ètò Aánu èyí ti ònkọwe wa, Njenga, tọ́ka si, àti bi o ṣé le ṣe ìrànwọ́ láti mú Ẹmi Olúwa tọ́ awọn ọmọde tí o wà nínú ìṣẹ́.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Hearing From Heaven: Listening for the Lord in Daily Life

Olúwa wà láàyè, Ó sì ń ṣiṣẹ́ ní óde òní, Ó ń bá olúkúlùkù àwọn ọmọ Rẹ̀ s'ọ̀rọ̀ ní tààràtà. Àmọ́ ní ìgbà míràn, Ó máa ń ṣòro láti rí I àti láti gbọ́ Ọ. Nípa yíyànnàná ìtàn ìrìn àjò ọkùnrin kan láti ní òye ohùn Ọlọ́run ní ìgbèríko Nairobi, ìwọ yíó mọ bí ó ti rí láti gbọ́ àti láti tẹ̀lé E.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Compassion International fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.compassion.com/youversion