Gbígbọ́ lati Ọ̀run: Títẹ́ Etí S'ílẹ̀ Sí Olúwa Nínú Ìgbésí Ayé Ojoojúmọ́Àpẹrẹ

Hearing From Heaven: Listening for the Lord in Daily Life

Ọjọ́ 3 nínú 5

“Èmi Ni Ni Ó Rán Mi Sí Ọ.”

Lọ́mọdé, mo fẹ́ràn láti máa gbọ́ ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìdè kúrò ní Íjíbítì. Àwọn ìtàn náà bá ayé mi mu rẹ́gí. Gbígbé nínú òṣì paraku dàbíi gbígbé bí ẹrú ní Íjíbítì.

Bí o bá ń d'àgbà ní àwọn ìgbèríko tí ó wà ní ìlú Nairobi, ní orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, yíó mú ọ ké pe Olúwa. Yíó mú kí o bẹ̀ Ẹ́ pé kí Ó gbà ọ́ lọ́wọ́ ipò òṣì tí ìdílé rẹ kò lè bọ́ nínú rẹ̀. Mímọ̀ pé Ọlọ́run yíó gbọ́ igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ tù mí nínú--Òun yíó wàá ràn mí lọ́wọ́. Bíi ti onísáàmù, mo ké jáde pé ‘’Ní ibo ni ìrànlọ́wọ́ mi yíó ti wá? Ìrànlọ́wọ́ mi yíó ti ọwọ́ Olúwa wa, tí ó dá ọ̀run àti ayé.”

Ìtàn Ìjádelọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fihàn pé Ọlọ́run gbọ́ igbe àwọn ènìyàn Rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Ó sì wá ọ̀nà láti dá wọn ní ìdè nítorí Ìjọba Rẹ̀. Ó sì rí ìwọ náà pẹ̀lú.

Síwájú síi, Ọlọ́run gbé ọkùnrin kan dìde láti kó àwọn ènìyàn Rẹ̀ kúrò nì oko ẹrú. Ọlọ́run mú un dá Mósè l'ójú pé Òun yíó wà pẹ̀lú rẹ̀: "ÈMI NI ni ó rán mi sí ọ." Mósè ní láti fi etí s'ílẹ̀ kí ó sì mọ ẹni tí ó ń pè é. Gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́, ó yẹ kí á rántí ẹni tí ó pè wá sí ìgbésí ayé tí à ń gbé. Jésù, ẹni tí ń jẹ́ ÈMI NI, wà pẹ̀lú wa. Òun ni Ó ń darí wa, tì ó sì ń mú kí á kún ojú ìwọ̀n láti ṣe iṣẹ́ tí ó pè wá láti ṣe.

Olúwa rí ìnira àwọn ọmọ ísírẹ́lì ní Íjíbítì Ó sì wá láti gbà wọ́n.

Ǹjẹ́ ò ń dúró de Ọlọ́run? Ṣé ó tilẹ̀ dàbí pé ó pẹ́ jù? À ń fi sùúrù dúró de Ọlọ́run nínú ipò òṣì, àìsàn, ọrọ̀ àti gbogbo ipò mìíràn nítorí a mọ̀ pé Ó ń gbọ́ àdúrà wa Ó sì rí ipò tí a ń d'ojú kọ.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Hearing From Heaven: Listening for the Lord in Daily Life

Olúwa wà láàyè, Ó sì ń ṣiṣẹ́ ní óde òní, Ó ń bá olúkúlùkù àwọn ọmọ Rẹ̀ s'ọ̀rọ̀ ní tààràtà. Àmọ́ ní ìgbà míràn, Ó máa ń ṣòro láti rí I àti láti gbọ́ Ọ. Nípa yíyànnàná ìtàn ìrìn àjò ọkùnrin kan láti ní òye ohùn Ọlọ́run ní ìgbèríko Nairobi, ìwọ yíó mọ bí ó ti rí láti gbọ́ àti láti tẹ̀lé E.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Compassion International fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://www.compassion.com/youversion