Gbígbọ́ lati Ọ̀run: Títẹ́ Etí S'ílẹ̀ Sí Olúwa Nínú Ìgbésí Ayé Ojoojúmọ́Àpẹrẹ

Bàbá rẹ Ọ̀run Mọ Gbogbo Ohun Tí O Níílò.
Ní ìgbà tí mo ti d'àgbà ní Nairobi, láti sọ ní ìwọnba, àsìkò náà ṣòro. Àwọn ọdún 1990s ní àìdánilójú púpọ̀. Ìjààgboro pọ̀, ó sì wá látárí ìpínyà láàárín ẹgbẹ́ tí ó ń ṣe àkóso àti àwọn tí wọ́n ń béèrè fún ìjọba tiwa-n-tiwa ọlọ́pọ̀-ẹgbẹ́. Àti pé ní àkókò ìjààgboro, àwọn tálákà ni wọ́n máa ń jìyà jù. Owó táṣọ́rẹ́ tí ó ń w'ọlé fún wọn ní àwọn tálákà gb'oju lé láti ra àwọn ohun tí wọ́n níílò lójoojúmọ́, irú ìpínyà bẹ́ẹ̀ a sì máa ń mú kí àwọn aláìní jìyà sí i.
Nítorí èyí, láti ìgbà kékeré, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kọ́ mí láti ní sùúrù.
Ní ìgbà tí kò bá sí ìdánilójú àbájáde rere, dídúró pẹ̀lú sùúrù lè nira gidi gan-an. Bàbá mi jẹ́ òṣìṣẹ́ agbowó-ojúmọ́, nítorí náà a gbára lé owó ojoojúmọ́ rẹ̀ fún àwọn ohun tí a níílò. Bí ó bá rí iṣẹ́, a ó jẹun. Bí ó bá jẹ́ pé ó nira láti wá iṣẹ́ kàn, a kò ni jẹun.
Bàbá mi ka Iwe Mátíù 6:25-34 fún wa ní àkókò ìfọkànsìn ẹbí wa ní alẹ́ ọjọ́ kan. Ó t'ọ́ka sí pàtàkì fífi ìrètí wa sí inú Jésù. Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù náà fún mi ní ìrètí láàrin àìdánilójú ayé. Gẹ́gẹ́ bí ẹbí, a sinmi nínú ìdánilójú pé Baba wa ọ̀run mọ gbogbo ohun tí a níílò. Mímọ̀ àti níní Jésù tó.
Bàbá wa ní ọ̀run mọ gbogbo ohun tí a níílò. Báwo ni èyí ṣe y'ani lẹ́nu tó? Ọlọ́run tí ó dá ohun gbogbo jẹ́ Ọlọ́run kannáà tí ó ní ọ̀nà pàtàkì láti bá àwọn àìní wa pàdé.
Ó rọrùn láti ṣe iyèméjì pé Òun yíó gbà wá. Kíni yíó ṣẹlẹ̀ tí kò bá pèsè ìrànlọ́wọ́ owó? Kíní yíó ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìlera mi? Pẹ̀lú ẹbí mi? Pẹ̀lú [fi àwọn ìṣòro rẹ sí ibi]? Kọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa, láìka gbogbo àkókáyà rẹ sí. Fi ara jì láti kà àti láti tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ bí o ṣe ń dúró de ìdádùn Ọlọ́run.
Nínú dídúró, ìrètí wa yíó ní agbára sí i. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run, a dúró de Ọlọ́run olóòótọ́ àti onífẹ̀ẹ́ tí inú rẹ̀ dùn láti pèsè àwọn ohun tí àwọn ọmọ Rẹ̀ níílò. Gbàdúrà sí Olùgbàlà rẹ:"Olúwa ọ̀wọ́n, gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ, mo máa ń ṣe àníyàn nípa ọjọ́ iwájú mi. Ṣùgbọ́n lónìí mo fi ìrètí mi sí inú Rẹ nítorí ìwọ ni olóòótọ́ ní ìgbà gbogbo nínú ayé mi. Amin."
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Olúwa wà láàyè, Ó sì ń ṣiṣẹ́ ní óde òní, Ó ń bá olúkúlùkù àwọn ọmọ Rẹ̀ s'ọ̀rọ̀ ní tààràtà. Àmọ́ ní ìgbà míràn, Ó máa ń ṣòro láti rí I àti láti gbọ́ Ọ. Nípa yíyànnàná ìtàn ìrìn àjò ọkùnrin kan láti ní òye ohùn Ọlọ́run ní ìgbèríko Nairobi, ìwọ yíó mọ bí ó ti rí láti gbọ́ àti láti tẹ̀lé E.
More