1
Matiu 1:21
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
BMYO
Òun yóò sì bí ọmọkùnrin, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu, nítorí òun ni yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
ஒப்பீடு
Matiu 1:21 ஆராயுங்கள்
2
Matiu 1:23
“Wúńdíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanueli,” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa”).
Matiu 1:23 ஆராயுங்கள்
3
Matiu 1:20
Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ro èrò yìí tán, angẹli Olúwa yọ sí i ní ojú àlá, ó wí pé, “Josẹfu, ọmọ Dafidi, má fòyà láti fi Maria ṣe aya rẹ, nítorí oyún tí ó wà nínú rẹ̀ láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni.
Matiu 1:20 ஆராயுங்கள்
4
Matiu 1:18-19
Bí a ṣe bí Jesu Kristi nìyí, ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrín Maria ìyá rẹ̀ àti Josẹfu, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí Josẹfu ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòtítọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójútì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.
Matiu 1:18-19 ஆராயுங்கள்