Ríràn nínú Èrò Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ríràn nínú Èrò Ọlọ́run

Ọjọ́ 4 nínú 6

Ìmúrasílẹ̀ máa ń bí Àfihàn

Gẹ́gẹ́ bí bàbá, n kì í gba ọmọbìnrin mi ẹni ọdún méjì láàyè láti mú àwọn nǹkan bí i ọ̀bẹ, nítorí pé kò tíì ṣetán láti ṣe bẹ́ẹ̀. Mo fẹ́ pa á mọ́, nítorí náà màá dípò bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ó lo ohun-ìṣeré ọmọdé. Gẹ́gẹ́ ví Bàbá wa, Ọlọ́run máa ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn nǹkan tí a kò tilẹ̀ tíì ṣetán láti gbámú. A lè bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún ohun tí ó níye lórí tàbí wúlò tí a mọ̀ pé ó lè pèsè, ṣùgbọ́ yóò dì í mú títí tí a ti múra sílẹ̀ tán láti gba àwọn ìbùkún Rẹ̀. Ó lè jẹ́ iṣẹ́ ìyanu náà ló múmú láyà wa, ṣùgbọ́n ìmúrasílẹ̀ w ani ó jẹ́ Ọlọ́run lógún.

Òpó ti ìmúrasílẹ̀ hànde nínú ìgbésíayé Dafidi. Ó lè ṣẹ́gun Goliath – jagunjagun ńlá aláìlórogún – nítorí pé ó ti ń fi ọgbọ́n náà kọ́ra lórí àwọn kìnnìún àti bíárì nígbà tí ó ń sọ agbo ẹran bàbá rẹ̀ (nígbà tí ẹnìkan kò sì rí i).

Gbogbo wa fẹ́ ṣe àfihàn ẹ̀bùn àti èrèdí wa ní kíákíá – ṣùgbọ́n ó pé láti múra sílẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìmúrasílẹ̀ máa ń wáyé ní ibi ìkọ̀kọ̀ níbi tí ẹnìkan kò ti rí ọ tàbí rí àwọn àṣeyọrí rẹ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹlọ̀míràn kò rí ọ, Ọlọ́run rí ọ. Ó ń kọ́ ọwọ́ rẹ níti ogun jíjà. Máṣe ní ìjákulẹ̀ nígbà tí ẹnikẹ́ni kò bá kí ọ fún àwọn iṣẹ́ ńlá tí ò ń ṣe. Máṣe kánjú kí àwọn ènìyàn lè rí ọ, nígbà tí Ọlọ́run kò tíì ṣetán fún ìgbáradì ayé rẹ.

Ọlọ́run ti pèsè Dafidi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọdékùnrin olùṣọ́-àgùtàn tí ó ń tọ́jú àwọn àgùtàn bàbá rẹ̀. Nítorí ìyẹn, Ọlọ́run kà á yẹ láti tọ́jú àwọn àgùtàn Israeli. Ó ti jẹ́ olóòótọ́ ní àwọn ohun kékeré. Ó sì ṣetán láti jẹ́ olóòótọ́ nínú àwọn ohun ńlá.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń sá fún ohun tó yẹ kó jẹ́ pèpéle fún ìfihàn àti àlùyọ wọn, ṣùgbọ́n ojú wọn máa ń ràn mọ́ àwọn àǹfààní àti ògo ńláńlá, nítorí náà wọ́n máa ń tàbùkù àwọn ojúṣe kékèké tí wọ́n lè sí àwọn ìlẹ̀kùn pàtàkì. Àwọn iṣẹ́ kékèké wọ̀nyẹn ni ìmúrasílẹ̀ tí yóò di àfihàn èrèdí rẹ fún ayé rí. Bí Dafidi bá ti fojú tẹ́ńbẹ́lú agbo àgùtàn bàbá rẹ̀ tí ó sì tàbùkù wọn, kò bá tí ní àbọ̀ láti jẹ́ fún Saulu nígbà tí àǹfààní náà dé nítorí pé àṣeyọríàti òtítọ́ rẹ̀ pẹ̀lú iṣẹ́ kékeré ni ó jẹ́ kí Saulu lè kà á yẹ fún àwọn ojúse ńlá.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí ló máa ń mú kí àwọn ènìyàn sá fún iṣẹ́ àti ojúṣe pàápàá jùlọ nínú ilé Ọlọ́run. Àwọn kan rò pé wọn kò ní rí àwọn; àwọn kan rò pé ó jẹ́ ìfàsìkòsòfò; àwọn kan rò pé ṣíṣe iṣẹ́ nínú ṣọ́ọ̀ṣì kò níye lórí tó. Ohun tí wọn kò mọ̀ ni pé nígbà tí o bá fi ohun gbogbo fún Ọlọ́run nígbà tí ẹnikẹ́ni kò rí ọ tàbí fún ọ lérè, ò ń tẹ́ pèpélé fún àfihàn rẹ ojọ́-iwájú ni.

Nítorí náà, máa ṣiṣẹ́ níbi ìkọ̀kọ̀. Máṣe lé ìdámọ̀, òkíkí àti owó. Máa lépa iye àti èrèdí. Máṣe sin Ọlọ́run nítorí ohun tí o fẹ́ gbà lọ́wọ́ rẹ̀, sìn ín nítorí pé ó fẹ́ fún un ní gbogbo ayé rẹ. Ọlọ́run tí ó sì rí ohun tí ò ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀ yóò fún ọ lérè.

Nípa Ìpèsè yìí

Ríràn nínú Èrò Ọlọ́run

Ṣe àwárí nínú ìgbésíayé Jeremiah àti Dafidi, pé o kò kéré jù láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésí-ayé èrèdí rẹ, sísin Ọlọ́run pẹ̀lú ohun tí o ní, níbi tí o wà. Kọ́ nipa ohun ìmúrasílẹ̀ fún èrèdí rẹ túmọ̀ sí, bí o ti ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn tí yóò bà á jẹ́, kí o sì múra sílẹ̀ láti gbé ìgbésí-ayé onítumọ̀, afògo-fún-Ọlọ́run tí yóò bùkún ayé.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/