Ríràn nínú Èrò Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ríràn nínú Èrò Ọlọ́run

Ọjọ́ 2 nínú 6

O kò kéré jù

Bóyá o tilẹ̀ rò pé o kéré láti tẹsẹ̀ bọ èrèdí Ọlọ́run fún ayé rẹ? Jẹ́ kí ìtàn ìgbésí ayé Dáfídì yìí fún ọ ní ìmísí.

Ọlọ́run sọ fún Samueli pé òún kábàámọ̀ sísọ Saulu di ọba lórí Israeli. Ó rán Samueli lọ sí ilé Jesse, nítorí pé Òún ti yan ọ̀kan nínú ọmọ Jesse gẹ́gẹ́ bí ọba. Àkọ́bí ọmọ Jesse wu Samueli, ẹni tí ó fi ojú jọ ọba lọ́la. Àmọ́ ṣá, Ọlọ́run sọ fún Samueli, ‘máṣe náání ìwò tàbí gíga rẹ̀, nítorí pé mo ti kọ̀ ọ́. Ọlọ́run kì í wo nǹkan tí ènìyàn ń wò. Ènìyàn ń wo òde, ṣùgbọ́n Olọ́run ń wo ọkàn.’ Ọlọ́run sì sọ èyí fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ọmọ Jesse, bí wọ́n ṣe ń tò lọ níwájú Samueli.

Lọ́kòótán, Samueli bi Jesse bí ó bá ní ọmọkùnrin mìíràn. ‘Ó ku àbíkẹ́yìn wọn,’ Jesse dáhùn. ‘Ó ń tún agbo àgùtàn ṣe.’ Samueli sọ pé, ‘lọ pè é wá; a kò ní jókòó àfi ìgbà tí ó bá dé.’Dafiidi dé. Gbogbo ìyókù sì jẹ́ ìtàn.

Ní kedere, Samueli tin í àwòrán bí ó ti yẹ kí ọba Israeli rí, àti pé iye ọjọ́-orí tí ó yẹ kí ó ní. Ṣùgbọ́n àwọn òṣùwọ̀n Ọlọ́run yàtọ̀. Bóyá ìwọ pẹ̀lú ní àwòrán tàbí àsìkò kan ní ọkàn tí o rò pé wà á ṣetán láti sin Ọlọ́run. Mo rántí bí mo ṣe sọ fún ara mi nígbà tí mow à ní ẹni ọdún mẹ́tàlá pé kò sí ohun tí ọmọdé bíì mi lé ṣe fún Ọlọ́run. Màá dúró kí n dé Yunifásítì.Ṣùgbọ́n èsì Ọlọ́run sí èrò mi hàn kedere: ‘Kín ló ṣe tóò bẹ̀rẹ̀ báyìí?’ Lóòótọ́ ni n ò ní ohun tí bíbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ pè fún. Dafidi kò ní ohun tí yẹ láti di ọba nígbà tí wọ́n fi àmì-òróró yàn án. Ó jẹ́ àbíkẹ́yìn. Lákọ̀ọ́kọ́, wọn kò pè é sí ìpàdé pẹ̀lú Samueli nítorí pé Bàbá rẹ̀ fi ojú tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùtàn tí kò ṣe pàtàkì.Ṣùgbọ́n òtítọ́ nip é, Ọlọ́run kàn ń wá àwọn ẹni tí kò gbẹ́kẹ̀lé agbára wọn, ṣùgbọ́n tirẹ̀. Paulu ṣàlàyé pé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó fún wa nítorí pé agbára Rẹ̀ mú wa dápé nínú àìlere wa.

Ọlọ́run yan Dafidi nítorí ti ó ní ọkàn tí Ọlọ́run ń wá. Gba ìyànjú pé o kò kéré jù láti rìn nínú èrèdí Ọlọ́run àti pé Ọlọ́run lè lò ọ́ kódà bí o kò bá ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àwòrán tó pé. Kí o sì rántí pé o kìí ṣe aṣiwèrè, kọ̀ láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà àìwàbí-Ọlọ́run tí àwọn irọ̀ rẹ ń rìn. Dípò bẹ́ẹ̀, ìgbọràn sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run ló máa ń gún ọ ní kẹ́sẹ́ sínú èrèdí. Nígbà tí àwọn mìíràn bá ń pẹ̀gàn rẹ fún àwọn ìdánilójú rẹ, máṣe gbàgbé pé ìdílé Dafidi kò náání rẹ̀ – wọ́n wá pàpà dúró bọ̀wọ̀ fún un níwájú rẹ̀. Gba ìyànjú! Nípasẹ̀ dídúró wámú fún Jesu, o ti bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò èrèdí.

Nípa Ìpèsè yìí

Ríràn nínú Èrò Ọlọ́run

Ṣe àwárí nínú ìgbésíayé Jeremiah àti Dafidi, pé o kò kéré jù láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésí-ayé èrèdí rẹ, sísin Ọlọ́run pẹ̀lú ohun tí o ní, níbi tí o wà. Kọ́ nipa ohun ìmúrasílẹ̀ fún èrèdí rẹ túmọ̀ sí, bí o ti ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn tí yóò bà á jẹ́, kí o sì múra sílẹ̀ láti gbé ìgbésí-ayé onítumọ̀, afògo-fún-Ọlọ́run tí yóò bùkún ayé.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/