Ríràn nínú Èrò Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ríràn nínú Èrò Ọlọ́run

Ọjọ́ 3 nínú 6

Èrèdí ta ni?

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ̀kùnrin, mo ní àlá kan láti di ayàwòrán-sinimá tó dára jù ní orílẹ̀-èdè mi. mo máa ń sábà ka àwọn ìwé, mo sì máa ń wo àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó koná mọ́ ìfẹ́-inú mi. Ṣùgbọ́n bí ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe gbilẹ̀ ta-gbòǹgbò si, mo rí i pé èrò mi kò ní gbòǹgbò nítorí pé láti ìgbà yìí wá, nipa mi nìkan ni. Kì í ṣe nipa Jesu rara. Ìgbà tí mo jọ̀wọ́ àlá mi fún un nìkan ni mo ní ìrírí ìmúṣẹ tòótọ́. Kò sí bí ìlépa rẹ ṣe lè rẹwà tó, bí Jesu kò bá sí ní ààrin gbùngbùn rẹ̀, o kò ní pàpà ní ìmúṣẹ.

Ìyàtọ̀ ńá wà láàrin ìlépa àti ìfojúsùn. Ìfojúsùn jẹ́ ìwòye oọjọ́-iwájú ẹnikan tí Ọlọ́run mí sí. Ìlépa jẹ́ ìwoye tìkalára rẹ nípa ọjọ́-iwájú. Ó jẹ́ ohun tí o ti pinnu láti dì. Ó jẹ́ nipa rẹ. Ọlọ́run ní orísun ìran-àfojúsùn, ṣùgbọ́n ìwọ nin orísun ìlépa. Àsìkò àti ìmúṣẹ ìlépa rẹ wà lọ́wọ́ rẹ, ṣùgbọ́n àsìkò àti ìmúṣẹ ìran-àfojúsùn rẹ àti èrèdí rẹ wà lọ́wọ́ Ọlọ́run. Ohun tó dára jù tí o lè retí nígbà tí o bá mú ìlépa rẹ ṣẹ ni ìtẹ́lọ́rùn ara-ẹni, ṣùgbọ́n mímú ìran-àfojúsùn rẹ ṣẹ máa ń mú ìmúṣẹ wá fun ọ àti fún àwọn ènìyàn tí ó wà ní àká ipá rẹ.

Àwọn ènìyàn tí ìlépa ń darí lè yọrí sí pípa àwọn mìíràn kí wọ́n lè débi ògo wọn, kódà wọ́n lè bi odindi orílẹ̀-èdè ṣubú, gẹ́gẹ́ bí Hitler ti ṣe. Ìran-àfojúsùn, ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, jẹ́ afúnni-níyè. Solomoni kọ ọ́ pé níbi tí kò bá sí ìran-àfojúsùn, àwọn ènìyàn á ṣègbé. George Muller, ajíhìnrere-káàkiri ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní 19th C, jẹ́ àpẹẹrẹ ẹni tí ó gbé ìgbésí-ayé ìràn-àjojúsùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó lá àlá mímú ayọ̀ tọ àwọn ọmọ òrukàn lọ. Ó lo ohun gbogbo tí ó ní láti bẹ̀rẹ̀ ilé àwọn ọmọ òrukàn, tí ó sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run fún ìpèsè lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Èrèdí rẹ̀ jẹ́ f;un ògo Ọlọ́run, àti ire àwọn mìíràn, kì í ṣe fún èrè ti ara rẹ̀.

Kí á padà sí ìtàn Dafidi; nígbà tí Samueli fi àmì-òróró yàn án gẹ́gẹ́ bí ọba, ó jẹ́ ìkéde èrèdí Ọlọ́run fún ìgbésí-ayé Dafidi. Àmọ́ ṣá, ìméṣẹ èrèdí Dafidi kò wáyé àfi lẹ́yìn ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Ní àwọn ọdún ìdúró wọ̀nyẹn, Dafidi dojúkọ Goliath, Saulu lé e ní ìlú, ó farapamọ́ sí aṣálẹ̀, ó ń gbé ayé ní ìsáré kiri, ó sì ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun. Láti lè borí gbogbo ìyẹn, ó níláti gbájú mọ́ ìran-àfojúsùn rẹ̀. A dán an wò, bí Ọlọ́run ṣe yí I padà láti ọmọdé olùṣọ́-àgùtàn sí ọba.

Nígbà tí ó bá ń rìn nínú èrèdí Ọlọ́run, nígbà mìíràn o lè má rí ìbáṣepọ̀ láàrin àwọn ìlérí ọlọ́run àti ipò rẹ lọ́wọ́lọ́wọ́. Ọlọ́run kò tíì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn ìlérí rẹ̀ lórí ayé rẹ kò tíì kùnà. Ó ṣe é ṣe pé ó ń ṣiṣẹ́ nínú rẹ láti yí ọ padà sí ọba láti ọmọdé ol]uṣọ́-àgùtàn.

Àwọn ìlérí wo ni Ọlọ́run ti fún ọ? Kín ni èrèdí rẹ? Ohun yòówù tí o lè máa dojú kọ, rán ara rẹ létí lójoojúmọ́ nipa ìran-àfojúsùn tí Ọlọ́run ti fún ọ fún ọjọ́-iwájú rẹ. èrèdí Rẹ̀ fún ayé rẹ yóò wá sí ìmúṣẹ.

Nípa Ìpèsè yìí

Ríràn nínú Èrò Ọlọ́run

Ṣe àwárí nínú ìgbésíayé Jeremiah àti Dafidi, pé o kò kéré jù láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ìgbésí-ayé èrèdí rẹ, sísin Ọlọ́run pẹ̀lú ohun tí o ní, níbi tí o wà. Kọ́ nipa ohun ìmúrasílẹ̀ fún èrèdí rẹ túmọ̀ sí, bí o ti ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn tí yóò bà á jẹ́, kí o sì múra sílẹ̀ láti gbé ìgbésí-ayé onítumọ̀, afògo-fún-Ọlọ́run tí yóò bùkún ayé.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/