Fẹ́ràn kí o sì máa Fẹ́ràn Síwájú síiÀpẹrẹ

Ìfẹ́ Ara-Ẹni
Níwọ̀n ọjọ́ méjì tó kọjá, a ti ṣe ìyàná àwọn àbùdá bí a ṣe ń fẹ́ni àti níní òye nípa ìfẹ́. Ìfẹ́ ń fifunni; ìfẹ́ ń dá wa padà sí orísun wá. Loni, mo fẹ́ rán ọ létí wípé ìfẹ́ jásí pé kí o fẹ́ràn ara rẹ
A rí ká nínú Mátíù 22:39, pé "Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ"
Báwo ni a ṣe lè fẹ́ràn àwọn míràn tí a kò bá fẹ́ràn ara wa? Kò lè ṣeéṣẹ. Ọ̀pọ̀ ìgbà, ni mo ti rí ènìyàn tí ó ń fi ìyà jẹ àwọn míràn tàbí gba ìjìyà fún ẹlòmíràn, a sì ṣe mí ní kàyéfì: Ta ló jẹ́ kí o ṣubú? Bi o tilè jẹ́ wípé ìbéèrè yìí lè dá bíi pé kò dojú àmì, mo pe ọ sí ìrìn-àjò kan lọ sínú Májẹ̀mú Láíláí, tí a ti sọ ìtàn Mefibóṣẹ́tì.
Mefibóṣẹ́tì jẹ́ ọmọ-ọmọ Sọ́ọ̀lu, tí ó ń gbé ní ìlú Lódébárì, tí a pè ní ìlú tí kò ní ètò, olórí kan, tàbí ìjọba lati ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ wá. Mefibóṣẹ́tì wá ní ìlú yìí nítorípé ó jẹ́ aláàbọ̀ ara ní ẹsẹ̀. Nígbàtí ó wà ní ọmọ ọdún márùn, ẹnìkan tí ó ń tọ́jú rẹ sọ sílẹ̀ èyí ló fà ti Mefibóṣẹ́tì fi wà ní irú ipò yí. Ó wá di ẹni tí a patì tí a sì gbàgbé pátápátá. Ìtàn náà sì tẹ́ síwájú títí dé ìwádìí Ọba Dáfídì láti ṣe àánú fún àtọmọdọ́mọ Sọ́ọ̀lu ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún Mefibóṣẹ́tì.
Mo mú ọ lọ nínú ìrìn-àjò kúkúrú yí sì inú Májẹ̀mú Láíláí nítorípé ìfẹ́ ara-ẹni ṣe pàtàkì bí a ṣe ńfi ìfẹ́ hàn sí àwọn míràn. Lọ̀pọ̀ ìgbà ni a máà ń rí àwọn ènìyàn tó lé nípa bí a ṣe dá wọn, a kò sì mọ ìdí tí wọ́n fi rí bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀ náà, iṣẹ́ wá ní láti nífẹ̀ẹ́ wọ́n kí a sì gbàdúrà fún àlàáfíà wọn pẹ̀lú
Nínú àgbékalẹ̀ wá yí, ní ìgbà míràn a lè bá ara wa ni Lòdèbàrì, ibi tí kò sì ètò, láìsí olórí, àti láìsí ìjọba nítorí pé ẹnikan ṣe okùnfà bí a ṣe ṣubú. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni a máà ún gbé ìgbé ayé yí láì ṣe sùúrù tàbí gba ìwòsàn, tí ó sì ń jẹ kí a rí ara wa bí ẹni tí kò yẹ ká nifẹ rẹ. Kìí ṣe èrò mi láti mú ọ gbàgbọ́ wípé ó lè dá gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣe àti pé ìwọ ni ẹni tí ó ṣe pàtàkì julọ ni àgbáyé; àfi, ìwọ! A ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n ìgbẹ́kẹ̀lé wá nínú Ọlọ́run gbà wá láàyè pátápátá láti nifẹ nítorípé Òun ni Ó kọ́kọ́ fẹ́ wá.
Ẹsẹ náà kò sọ wípé láti fẹ́ràn àwọn míràn, àti bí ó bá rí àyè, fẹ́ràn ara re; nǹkan tí ó sọ ní pé nifẹ àwọn míràn GẸ́GẸ́ BÍ ó ṣe nifẹ ara rẹ. Ìbéèrè mi fún ọ lónìí ní pé: Ǹjẹ́ ó fẹ́ràn ara rẹ bi o ṣe wá yí? Àwọn kọ̀rọ̀ wo ni ìgbésí ayé rẹ ni ó ti nílò ìyípadà láti nifẹ ara rẹ àti àwọn míràn ni ọ̀nà tó mú ìlera dání?
Bí a ṣe ńdáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lè sún ọ dé ibi tí ìyípadà yíò wá, láti ṣe àtúnṣe, àti láti sá agbára. Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ó gba mi gbọ́ pé, àsìkò-ká-sìkò tí a bá fi ara wa jì láti nifẹ ara wa gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ wá ló tọ́. A kò lè fúnni ní nǹkan tí a kò ní.
Ìbéèrè mi ti ó tẹle fún ọ ní pé: Tá ló já ọ kulẹ̀? O gbọdọ̀ dáríjì àwọn tí ó ṣe àṣìṣe sì ọ kí o baà leè bẹ̀rẹ̀ ìlànà ìmúláradá rẹ kí o sì rii pé Ọlọ́run fi ohun gbogbo tí ó ṣe pàtàkì sínú rẹ kí o lè ṣe àfihàn ìfẹ́ àti oore Rẹ̀
Mó pé ọ kí o fí àkókò sílẹ̀ làti mọ ara rẹ, láti fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí ara rẹ, láti nifẹ ara rẹ, ati láti rán ara rẹ leti pe ti ẹmi ba wa ninu rẹ, ìrètí wa láti ṣe ohunkóhun. Nítorípé ẹnìkan jẹ́ kí ó ṣubú kò yẹ kí ó ṣe ìdíwọ́ fun ọ lati ṣe aṣeyọri idi ti o fi wá sí ayé; ni ìdákẹ́jí, Ọlọrun nlo awọn akoko ati awọn ìtanijí wọ̀n yẹn lati di ọ ní àmùrè lati ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn mìíràn.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ṣíṣe ayẹyẹ ìfẹ́ kọja ṣíṣe-é ní ọjọ́ kan pato; ó jẹ́ ìgbésí ayé tí ń rán àwọn ẹlòmíràn létí ní ìgbà gbogbo pé ìfẹ́ Ọlọ́run wá láti mú wa ní ara dá, mú wa padà bọ̀ sípò, àti láti fún wa ní ìyè tí ń p'òkìkí oore rẹ̀. Mo pè ọ́ láti ka ètò ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́ta l'órí ohun tí ifẹ í ṣe àti ohun tí ó jọ l'áti ní ìfẹ́ àwọn ẹlòmíràn bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí á ṣe.
More