Fẹ́ràn kí o sì máa Fẹ́ràn Síwájú síiÀpẹrẹ

Ní Ìgbà Tí Ó Bá Ṣòro Láti Ní Ìfẹ́
Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àkòrí tí ó wọ́pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ àyọkà, ìwé, orin, àti àwọn ohun mìíràn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa yóò tilẹ̀ jẹ́ amòye nínú rẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ èrò tí a fi ara mọ́. Àmọ́, ó jẹ́ ọ̀kan l'ára àwọn àkòrí tí a sọ̀rọ̀ àti kọ nípa rẹ̀ jù nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan ní ààárín àwọn èrò tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa ti ní àríyànjiyàn, iyèméjì, àti ìtàn ayọ̀ pẹ̀lú ìtàn ìrora tí ó pọ̀ jù.
Nípa ìwà, a máa ń kà mí sí ẹni tí ó rọrùn fún láti ní ìfẹ́. Ṣùgbọ́n, mo ti ní àwọn àkókò tí ìfẹ́ wà l'ára àwọn ìpèníjà tí ó tóbi jù lọ fún mi.
Ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìdí tí ìbáṣepọ̀ ṣe ń múlẹ̀; àìsí ìfẹ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìdí tí ó wọ́pọ̀ ju ti ìbáṣepọ̀ ṣe ń fi orí ṣánpọ́n. Báwo ni a ṣe dé ibẹ̀?
Ìdáhùn ni pé ìfẹ́ túmọ̀ sí fífifúnni. Nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a rí ọ̀kan nínú àwọn ẹsẹ̀ tí gbogbo ènìyàn mọ̀ jù, tí ó sọ wí pé: "Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣugbọn kí ó lè ní ìyè ainipẹkun." Johanu 3:16
Ní ìgbà tí Ọlọ́run fẹ́ràn aráyé, ó FÚN wa ní ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo. Ìṣẹ̀dá wa máa ń fẹ́ jẹ́ kí a tara láti ronú nípa àlàáfíà àti ìdẹ̀rùn, àti ànfààní. Àfojúsùn wa máa jẹ́ ọ̀nà láti fi ṣe àwòfín (sí ara wa), kí á sì gbàgbé ohun tí ó ṣe kókó nípa ìfẹ́.
Ìfẹ́ ń FIFÚNNI, èyí tí ó túmọ̀ sí pé a darí àfojúṣùn wa sí àwọn ẹlòmíràn. Ìfẹ́ ń fifúnni láì fi àyídáyidà ṣe, ìfẹ́ ń fifúnni bí rògbòdìyàn tilẹ̀ wà, ìfẹ́ sì ń tẹ̀ síwájú láì fi ti ọgbẹ́ ṣe.
Ọlọ́run kò nílò láti fi Ọmọ rẹ̀ léni lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ó fẹ́ fi ìfẹ́ rẹ̀ fún wa hàn ní ọ̀nà tí ó hàn gbangba. Gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀, kò sí ohunkóhun tí a ṣe lati jèrè ìfẹ́ rẹ̀; ó ní ìfẹ́. Òun kò kàn ní ìfẹ́ wa ní kété tí a bá wà dé ìpele kan nínú ìdàgbàsókè tí a ti lè gbà á. Ó fi Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún wa láti fi ìfẹ́ ńláǹlà tí ó ní fún wa hàn.
Ní ìgbà tí a bá pè mí ní ìjà láti ní ìfẹ̀ẹ́ àwọn tí ó ṣe ohun tí ó pa mí l'ára, mo rántí bí Ọlọ́run ṣe darí mi l'áti gba àdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọ̀nà kan náà bí a ṣe ń gba àdúrà fún àwọn tí a ní ìfẹ̀ẹ́ tọkàntọkàn. Mo gba àdúrà fún wọn, fún ẹbí wọn, fún iṣẹ́ wọn, fún ètò ìṣúná wọn, fún ìṣe-dáradára wọn, fún ìlera wọn nínú ìmọ̀lára àti nínú ẹ̀mí. Ìwòye mi nípa wọn yí padà pátápátá nítorí pé Ọlọ́run gbà mí ní ààyè láti rí i pé kìí ṣe nípa pé bóyá wọ́n ní ẹ̀tọ́ l'áti rí ìfẹ́ gbà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ó ṣe ni ní àánú pé, nínú ìrora, a kọ̀ láti fifúnni tàbí gbà á. Gbogbo ènìyàn, àti àwọn tí ó pa wá l'ára pàápàá, ni ó nílò ẹnìkan tí yó ní ìfẹ̀ẹ́ wọn.
À ń pè wá ní gbogbo ìgbà l'áti fifúnni, l'áti ní ìfẹ̀ẹ́, láì retí pé àwọn tí ó ti mú ìnira wá sí inú ayé wa yóò yí padà, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdánilójú pé ìfẹ́ wa lè ní ipa l'órí ayé wọn.
Ní ònìí, mo pè ọ́ ní'jà pé kí o mọ̀ọ́mọ̀ ya ìṣẹ́jú mẹ́ta sí ọ̀tọ̀ l'áti gba àdúrà fún ayé àwọn tí ó ti pa ọ́ l'ára kí o sì gbé ohùn àdúrà sí òkè fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìwọ yóò ti ṣe fún àwọn tí ó rọrùn láti ní ìfẹ́ sí. Bèèrè pé kí Ọlọ́run bá àìní wọn pàdé, gbé ohùn sí òkè fún ìyanu, kí o sì gbé ohùn sí òkè l'áti rí ìfarahàn Jésù nínú ayé wọn. Ó dá mi l'ójú pé ní ìgbà tí o bá parí àdúrà yìí, bí ìwọ yóò ṣe rí wọn yóò yàtọ̀; ìwọ yóò ní òyé pé ìfẹ́ ti di ohun gbòógì nínú ọkàn rẹ, àti pé ìwọ yóò yí padà l'áti di ẹni tí yóò yí àwọn tí wọ́n yí ọ ká padà.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ṣíṣe ayẹyẹ ìfẹ́ kọja ṣíṣe-é ní ọjọ́ kan pato; ó jẹ́ ìgbésí ayé tí ń rán àwọn ẹlòmíràn létí ní ìgbà gbogbo pé ìfẹ́ Ọlọ́run wá láti mú wa ní ara dá, mú wa padà bọ̀ sípò, àti láti fún wa ní ìyè tí ń p'òkìkí oore rẹ̀. Mo pè ọ́ láti ka ètò ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́ta l'órí ohun tí ifẹ í ṣe àti ohun tí ó jọ l'áti ní ìfẹ́ àwọn ẹlòmíràn bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí á ṣe.
More