Fẹ́ràn kí o sì máa Fẹ́ràn Síwájú síiÀpẹrẹ

Love and Keep Loving

Ọjọ́ 2 nínú 3

Èdè Àìmọ̀

"Bí èmi tilẹ̀ lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí ènìyàn àti ti angẹli, tí n kò bá sì ní ìfẹ́ mo kàn ń pariwo bí ago lásán ni tábí bí i kimbali olóhùn gooro." 1 Kọrinti 13:1 BYO

Ní bí oṣù mélòó kàn sẹ́yìn, a ṣèbẹ̀wò sí onírúurú orílẹ̀-èdè pẹ̀lú àwọn ẹbí mi, ọ̀kan lára ​​àwọn ibi wọ̀nyí sì ń sọ èdè kan tí mi ò mọ̀. O jẹ́ ohun tó ń bani lẹ́rù bí mo ṣe fi etí sí àwọn ènìyàn ti o yí mí ká tí wọ́n jíròrò lórí ohun tí kò yé'mi. Bí mo ṣe ń fi etí sí wọn, tí mo ṣì ń béèrè fún ìtọ́sọ́nà jẹ́ ọpọlọpọ ìpèníjà. Ọpẹ́lọpẹ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ tí o dára jù lọ, mo le ṣe àyẹ̀wò àwọn àmì àti àwọn ọ̀rọ̀ láti lè túmọ̀ rẹ sí Gẹ̀ẹ́sì.

Èyí mú mí rántí pé nígbà mìíràn ifẹ a máà di èdè àìmọ̀ tí a kò bá mọ orísun rẹ. Nígbà míràn, à ń rìn ìgbésí ayé bí mo tí ṣe ṣe ni àkókò ìsinmi pẹ̀lú ẹ̀rọ ìṣe àyẹ̀wò, mo ń gbìyànjú láti mọ gbogbo nǹkan tàbí ibi tí o yẹ kí a lọ, nígbà tí à ǹ fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn. Ẹ̀rọ ìṣe àyẹ̀wò yí gbà mí láyè láti ní òyè awọn ọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n kò jẹ́ kí n le sọ èdè náà.

Mímọ orísun ìfẹ́ túmọ̀ sí mímọ Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ló wà láti fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n láì jẹ́ pé a ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, a ó máa gbìyànjú nínú okun wa ohun tí ó yẹ kí a ṣe tàbí bí a ṣe lè fi ìfẹ́ yìí hàn. Ọ̀kan lára àbùdá àwọn ẹni tí ó ń tẹ̀ lé Jésù ní ìfẹ́. Báwo ní o tí ṣe pàtàkì láti rántí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù, nígbàtí o sọ pé gbogbo ènìyàn yóò mọ pé ọmọ-ẹhin Rẹ̀ ní wa nípa èyí: bí ẹ bá ní ìfẹ́ sí ara yín. Ìyàlẹ́nu ló má njé fún wá ní ọ̀pọ̀ ìgbà ìdí tí àwọn ènìyàn kò ṣe fẹ́ láti mọ ohunkóhun nípa ẹ̀sìn Krìstẹ́nì. Ṣé kì í ṣe pé àwọn èèyàn ò mọ̀ wá sí ẹni tí o nífẹ̀ẹ́? Húù!

Mo lérò pé ọ̀kan lára ​​àwọn ìpèníjà ńlá jùlọ fún mi nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni rírán àwọn ènìyàn létí pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ju ohunkóhun mìíràn lọ, àti fún èyí, a kò lè nífẹ̀ẹ́ nínú agbára wa, tàbí ní bí a ṣe túmọ̀ ìfẹ́ wa; a gbọ́dọ̀ ma padà lọ sí orísun ìfẹ́ lojoojúmọ́ ati ní gbogbo ìgbà. Ìfẹ́ ló ṣáájú òfin; ìfẹ́ ló tún ṣáájú ìyípadà; ní òtítọ́, mo lé sọ pe láìsí ìfẹ́, o kò le rí ìyípadà kankan. Àwọn tí o fi ìfẹ́ han bí tí Jésù nítòótọ́ ní àǹfààní láti ní ipa tó máa wà pẹ́ títí lórí aye àwọn ènìyàn ju àwọn tí wọ́n kàn ní ipá fúnni láti gbé gẹ́gẹ́ bí Jésù.

Lónìí, ìkésínie mi ni láti padà sí orísun ìfẹ́ láti fi ìfẹ́ tí a fi dá wà mọ̀ hàn. Béèrè lọwọ Ọlọ́run fún àwọn ìmọràn ẹdá láti nífẹ̀ẹ́ sí àwọn tí o nílò láti rí I pé a fìfẹ́ hàn sí wọn. Pé wọn kí wọn wá jẹun, fi ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ ránṣẹ́ sí wọn, kí o sí bù kún ìgbésí ayé wọn ní ọ́nà tó fi hàn pé lóòótọ́ ni pé ìfẹ́ tí ọlọ́run ní sí wà kí í kùnà àti pé ó sì fi hàn nínú ìgbésí ayé rẹ; ní ọ̀nà yìí, o lè sọ Kristi di mímọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn.

Nípa Ìpèsè yìí

Love and Keep Loving

Ṣíṣe ayẹyẹ ìfẹ́ kọja ṣíṣe-é ní ọjọ́ kan pato; ó jẹ́ ìgbésí ayé tí ń rán àwọn ẹlòmíràn létí ní ìgbà gbogbo pé ìfẹ́ Ọlọ́run wá láti mú wa ní ara dá, mú wa padà bọ̀ sípò, àti láti fún wa ní ìyè tí ń p'òkìkí oore rẹ̀. Mo pè ọ́ láti ka ètò ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́ta l'órí ohun tí ifẹ í ṣe àti ohun tí ó jọ l'áti ní ìfẹ́ àwọn ẹlòmíràn bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí á ṣe.

More

A fé dúpẹ́ lọ́wọ́ Ginny Rivera fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ̀ si, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.instagram.com/willnginny/