Má ṣe àníyàn ohùn kankanÀpẹrẹ

Ìgbésí Ayé Láìsí Àníyàn
A ti jọ ṣàwárí pé àníyàn kì í ṣe ète Ọlọ́run tó dára jù lọ fún wa. A tún ti wá mọ̀ dájú pé àdúrà ni aporó àníyàn, ó sì máa ń fún ni ní ìbàlẹ̀ ọkàn.
Àmọ́ báwo la ṣe lè dènà àníyàn kó tó di pé ó gbà ọkàn wá.
Mo gbàgbọ́ pé ohun tó lè yanjú ọ̀ràn náà ni pé kí á tulẹ̀ ìgbésí ayé àlàáfíà.
Bíbélì sọ èyí nínú Róòmù 12:18:
'Ẹ sa gbogbo ipá yín láti gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.'
Gbogbo èèyàn. Èyí kan àwa fúnra wa pẹ̀lú!
Tí a bá ń bá àwọn ẹlòmíràn jà tàbí tí à ń bá ara wa jà, a ó ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí yóò kó àníyàn bá wa. Ṣùgbọ́n tí a bá ti mọ bí èèyàn ṣe ń gbé ìgbé ayé àlàáfíà, yíò yíò rọrùn fún wa láti gbé láìsí àníyàn.
Ọgbọ́n ń kó ipa pàtàkì nínú gbígbé ní àlàáfíà.
- Dípò kí o náwó yààyàà, máa fi owó pa mọ́. Èyí yíò fún ọ ní ìbàlẹ̀ ọkàn lórí ìṣúnná rẹ.
- Dípò tí pípẹ́ ìṣẹ́jú mẹ́wàá dé ẹnu iṣẹ́ lójoojúmọ́, dé bẹ̀ ní ìṣẹ́jú mẹ́wàá ṣáájú àkókò. Èyí yíò fi ọkàn rẹ á balẹ̀ pé o ní orúkọ rere níbi iṣẹ́ rẹ.
- Dípò tí wàá fi máa lọ́ tìkọ̀tìkọ̀ láti dìde nílẹ̀ tí gbogbo àkókò fi lọ tán, dìde ní kùtù kí o sì lo àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ rẹ. Èyí yíò fi ọkàn rẹ á balẹ̀, wàá sì mọ̀ pé o ti mójútó àti borí lọ́jọ́ yẹn.
Àwọn ìgbésẹ̀ tí ó bọ́gbọ́n mu bíi àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí lè jẹ́ àmúlò ní gbogbo agbọndan ayé wa. Gbígbé ìgbé ayé òdodo kìí ṣe 'èrò rere' lásán, ìwé mímọ́ gbà á níyànjú nítorí ó ń so èso àlàáfíà nínú ìgbésí ayé wa.
Ìròyìn ayọ̀ nípa àlàáfíà Ọlọ́run, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ni pé a kò lè kó ìdààmú báa. Ẹ̀bùn tó wá látọ̀dọ̀ Olùfúnni ní Ẹ̀bùn ti Ó ga jùlọ ni.
Jòhánù 14:27 sọ pé:
"Mo fi ẹ̀bùn kan sílẹ̀ fún yín - ìyẹn ni ìbàlẹ̀ ọkàn. Àlàáfíà tí mo fún yín sì jẹ́ ẹ̀bùn tí ayé kò lè fúnni. Nítorí náà, ẹ má ṣe dààmú tàbí kí ẹ̀rù bà yín."
Máa gbé ìgbé ayé àlàáfíà.
Máa gbé ìgbé ayé òdodo.
Máa fi ọgbọ́n gbé ìgbésí ayé rẹ.
Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èlò fún ìgbésí ayé tí kò ní àníyàn.
Ìgbésè Tó Kàn
Paríparí rẹ̀, kó Jòhánù 14:27 sórí.
Nígbàkigbà tí àníyàn bá kanlẹ̀kùn rẹ, rántí pé Ọlọ́run fún ọ ẹ̀bùn àlàáfíà, ó sì jẹ́ ẹ̀bùn tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ.
Fún àwọn ìlànà ìfọkànsìn míì láti CBN Europe, tàbí láti mọ̀ sí i nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí, jọ̀wọ́ tẹ
níbí.
Nípa Ìpèsè yìí

Àníyàn máa ń gba àkókò wa, ó máa ń gba agbára wa, ó sì máa ń gba ìbàlẹ̀ ọkàn wa. Kí wá ni ìdí tí a fi ń ṣe àníyàn? Nínú ìfọkànsìn ọjọ́ mẹ́ta yìí, a óò wo àníyàn, ìdí tí a fi ń ṣe é, àti bí a ṣe lè jáwọ́ nínú rẹ̀.
More