Má ṣe àníyàn ohùn kankanÀpẹrẹ

Worry for Nothing

Ọjọ́ 1 nínú 3

Kíni ìdí tí a ṣe ń ṣe àníyàn?

Gbogbo wa la máa ń ṣàníyàn nígbà míì nínú ìgbésí ayé wa, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Fún àpẹrẹ, owó tí a kò rò tẹ́lẹ̀ pé a máa san máa ń wọlé wá, láì tíì ṣètò iye tá a máa ná, a sì máa ń ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa san án.

Nígbà míràn, tí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú péré bá lé lẹ́yìn tí a sọ pé èèyàn wa kan yíò délé, gbogbo àkókò yí la sì fi máa ṣàníyàn pé ó ṣeé ṣe kí nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ sí i.

Ọmọ wa lọ sí ilé ìwé fún ìgbà àkọ́kọ́, o sì máa ṣàníyàn nípa bó ṣe ń lọ àti bó ṣe ń bọ̀.

Gbogbo wa la ní àwọn ìgbà tí a kò lè ṣàkóso ara wa, tí a kò sì lè mú kí gbogbo ohun tó ń lọ nínú ìgbésí ayé wa wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. A máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀, a sì máa ń gbìyànjú láti mọ ohun tá a lè ṣe láti yanjú ọ̀ràn kan tàbí ìṣòro kan, nígbà míì a kì í lọ bá ẹni tí ó jẹ́ Orísun wa.

Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn bìkítà, gbogbo wa la ní àwọn nǹkan tá a bìkítà nípa wọn, èyí sì dára. Àmọ́, tá a bá ń ṣàníyàn, ó lè mú ká pàdánù ayọ̀ àti okun tá a nílò láti gbé ìgbé ayé wa.

Dúró díẹ̀ kí o ka ẹsẹ Bíbélì tòní tí ó wà ní Matiu 6:25-34.

Mátíù kọ́kọ́ mẹ́nu kan àwọn nǹkan tí gbogbo wa nílò, bíi oúnjẹ, ohun mímu àti aṣọ.

A mọ̀ọ́. Mátíù sì mọ̀ọ́. Ọlọ́run mọ̀ọ́!

Ó dá wa lójú pé Ọlọ́run mọ ohun tá a nílò láti gbé ìgbé ayé tó dára, ó sì ti ṣètò láti pèsè rẹ̀ fún wa.

Mátíù tẹ̀síwájú láti ṣàpèjúwe èyí nípa sísọ pé àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pàápàá máa ń lọ láti ọjọ́ dé ọjọ́, wọ́n sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìpèsè Baba. Wọn kì í fò kiri kí wọ́n sì máa ṣàníyàn nípa oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ tàbí ibi tí wọ́n máa kọ́ ìtẹ́ wọn sí – gbogbo rẹ̀ ni ọlọ́run pèsè fún wọn lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ẹ̀dá.

Ǹjẹ́ àníyàn wa lè mú ká ṣe àṣeyọrí kankan? Àbí ńṣe ló wulẹ̀ ń gba ayọ̀ kúrò lọ́kàn wa?

Mátíù fi kún un pé àwọn òdòdó inú pápá máa ń múra dáadáa ju bá a ṣe rò lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń dà wọ́n nù lẹ́yìn tí ọjọ́ náà bá ti parí. Ẹ ò rí i pé a níye lórí gan-an lójú Ọlọ́run tá a bá fi wé àwọn ẹyẹ wọ̀nyí! Rántí wípé Nígbàtí o bá ń ṣe àníyàn. Ó nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì bìkítà nípa ohun tó o nílò. Ó tiẹ̀ bìkítà nípa ohun tó o fẹ́! Ọlọ́run mọ ohun tó wà lọ́kàn wa àti ohun tá a nílò.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́, báwo la ó ṣe ta yọ nínú ayé tí ó ti sọnù tí ó sì ń wá àtúnṣe bí a bá ń gbé ìgbésí ayé wa tí a sì ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun kan náà tí àwọn tí kò tíì mọ Ọlọ́run ń ṣe?A gbọ́dọ̀ dènà àníyàn kí a sì jà fún àlàáfíà.

Ẹ máa ṣe gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run dípò ti ara yín, Òun yóò sì bójú tó gbogbo nǹkan yòókù. Máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀nà Rẹ̀, Òun yóò sì pèsè gbogbo ohun tí o nílò fún ọ.

Má ṣàníyàn nípa ọjọ́ iwájú, Ọlọ́run mo ètò ti ó ní fún wa (wo Jeremáyà 29:11) àti pé gbígbẹ́kẹ̀lé e, ó dára.

Àwọn ìgbésẹ̀ tó kàn

Mọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú Jeremáyà 29:11 sórí.

Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn, ka ẹsẹ Bíbélì yìí sókè tàbí kó o sọ ọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́.

Rán ara rẹ létí wípé Ọlọ́run mọ ètò tí ó ní fún ayé rẹ̀! Simi sínú ìmọ̀ yìí.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worry for Nothing

Àníyàn máa ń gba àkókò wa, ó máa ń gba agbára wa, ó sì máa ń gba ìbàlẹ̀ ọkàn wa. Kí wá ni ìdí tí a fi ń ṣe àníyàn? Nínú ìfọkànsìn ọjọ́ mẹ́ta yìí, a óò wo àníyàn, ìdí tí a fi ń ṣe é, àti bí a ṣe lè jáwọ́ nínú rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọwọ́ CBN Europe fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí iwájú síi, ṣe àbẹ̀wò: https://www.cbneurope.com/yv