Má ṣe àníyàn ohùn kankanÀpẹrẹ

Worry for Nothing

Ọjọ́ 2 nínú 3

Bí O Ṣe Lè Borí Àníyàn

Jésù kò fi wá sílẹ̀ nínú àníyàn wa. Ó mọ̀ pé a máa dojú kọ ọ́, ó sì ti fún wa ní ìlànà tí a lè tẹ̀ lé nígbà tó bá dé bá wa. A kò fi wá sílẹ̀ láì ni ìrànlọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ọgbọ́n tó wúlò gan-an ló wà nínú Bíbélì nígbà tí wàhálà bá dé.

Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú Fílípì 4:6-7.

Àgbàyanu! A ní ọ̀nà tí a lè gbà borí àníyàn èyí tí a kọ sínú Ìwé Mímọ́!

Àníyàn + Àdúrà (Àwọn Àìní + Ọpẹ́) = Ìbàlẹ̀ Ọkàn.

Nígbà tí ìwé àti sinwó bá dé- gbàdúrà. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún owó tó ń wọlé fún yín àti gbogbo ohun tí Ó ti ṣe nínú ọ̀ràn ìṣúnná owó yín.

Nígbà tí wọn kò tíì délé - gbàdúrà. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àjọṣepọ̀ àti ìfẹ́ tí ẹ ní.

Nígbà tí ọmọ rẹ bá kọ́kọ́ lọ sí ilé àbójútó ọmọdé - gbàdúrà. Dúpé lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ẹ̀bùn ọmọ àti ìpèsè ilé ìtọ́jú àwọn ọmọdé.

Lẹ́yìn tí o bá ti gbàdúrà, tí o dúpẹ́, tí o sì sọ ohun tí o nílò, jẹ́ kí àlàáfíà tí Ọlọ́run nìkan ṣoṣo lè fúnni wá sórí rẹ.

Ó lè máà tètè dé, o lè ní láti padà tọ Ọlọ́run lọ nípasẹ̀ àdúrà, àmọ́ èsì yóò dé. Ọlọ́run ti ṣèlérí rẹ̀.

Ó lè máa ṣe wá bíi pé kí á mú ẹ̀ro ìbánisọ̀rọ̀ wa tàbí ká sọ ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn fún ẹnìkan. Àkókò àti ààyè fún èyí wà. Àmọ́, ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà borí àníyàn ni pé kí á kọ́kọ́ tọ Ọlọ́run lọ. Kì í ṣe pé èyí ń bọlá fún Ọlọ́run tí ó sì ń bùkún fún-Un nìkan, àmọ́ ó tún bá wa dẹ́kun kí àníyàn máa pọ̀ sí i.

Ọlọ́run bìkítà, ẹ̀yin ọ̀rẹ́. Ó fẹ́ kí á wá sí ọ̀dọ̀ Òun dípò tí aà bá fi máa jókòó sínú ọ̀gbun àníyàn tí kò ní òpin. (Ka 1 Pétérù 5:7.)

Ohun àgbàyanu tí ó wà nínú ìṣirò tí a rí nínú ìwé mímọ́ ni pé a lè lò ó níbikíbi, nígbàkigbà. Nígbà tí ìgbàgbọ́ wa bá dá lórí àjọṣepọ̀, tí kì í ṣe ẹ̀sìn kan, a mọ̀ pé a lè tọ Ọlọ́run lọ nípasẹ̀ àdúrà, nígbàkigbà tí àníyàn bá yọjú.

Àníyàn + Àdúrà (Àwọn Ohun Tá A Nílò + Ọpẹ́) = Ìbàlẹ̀ Ọkàn.

Má ṣe jẹ́ kí ọ̀tá gbà ìdùnnú ọjọ́ òní lọ́wọ́ rẹ. Kó àwọn àníyàn rẹ lé Jésù lọ́wọ́ kí o sì jẹ́ kí Ó fi àlàáfíà kún inú rẹ.

Ìgbésẹ̀ Tó Kàn

Bíi ti ọjọ́ àkọ́kọ́, a máa ṣe àkọ́sórí ẹsẹ Bíbélì kan tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti borí àníyàn.

Ka Fílípì 4:6-7. Máa kàá títí oó fi mọ̀ọ́ dáadáa.

Ní báyìí, nígbàkigbà tí o bá ń ṣàníyàn, wàá rí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní àkókò yẹn.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Worry for Nothing

Àníyàn máa ń gba àkókò wa, ó máa ń gba agbára wa, ó sì máa ń gba ìbàlẹ̀ ọkàn wa. Kí wá ni ìdí tí a fi ń ṣe àníyàn? Nínú ìfọkànsìn ọjọ́ mẹ́ta yìí, a óò wo àníyàn, ìdí tí a fi ń ṣe é, àti bí a ṣe lè jáwọ́ nínú rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ l'ọwọ́ CBN Europe fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí iwájú síi, ṣe àbẹ̀wò: https://www.cbneurope.com/yv