Gbígbẹ́ Ayé Ọ̀tun: Ní Ọdún TuntunÀpẹrẹ

Living Changed: In the New Year

Ọjọ́ 4 nínú 4

Mímú Ìyàtọ̀ wá nípasẹ̀ Àwọn Ẹ̀bùn Rẹ

Ọdún titun nìyí. Ìkọ̀wé tí ó mọ́ ló wà ní iwájú rẹ àti àwọn ànfàní àìlópin. Ìwọ̀n Ọdún sí àkókò yí, nígbà tí o bá wo àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù tí ó ń bọ̀ níwájú yí sẹ́yìn, kíni o fẹ́ láti rí? Ṣé o fẹ́ ri pé o ṣe oun tí ó yàtọ̀ nínú ayé yìí àti ní ìjọba Ọlọ́run?

Bóyá o mọ̀ tàbí o kò mọ̀, Ọlọ́run fi àwọn ohun kan sí ọ̀nà rẹ ó ṣì fún ọ ní ànfàní kí Ó lè fi agbára kún ọgbọ́n ìm ọ o sẹ oríṣiríṣi fún ọ, kí O le pèsè rẹ sílẹ̀ fún èrèdí rẹ.  

Gbogbo àwọn ìrírí ìgbésí ayé mú ọ jẹ́ aláìlẹgbẹ. Wo àwọn ẹ̀bùn àbímọ́ tí ó ní tí Ọlọ́run ti fún ọ, àwọn ànfàní oríṣiríṣi tí o ti ní, àti àwọn ìmọ̀ọ́ṣe rẹ. Ronú nípa ibi o ti dàgbà, ibi tí o ti rìn ìrìn àjò dé, ohun tí o ti kọ́. Bóyá o lóye àwọn àṣà oríṣiríṣi kí o sì lè darapo mọ́ àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé, tàbí bóyá o tilẹ̀ ṣe ohun àṣà kan tí ó lè ṣe ìwúrí tí ó lè tanijí lati jíjà ẹ̀tọ́. Àwọn ìrírí oríṣiríṣi tí o ti ní nínú ìgbésí ayé rẹ yìí lè dà bí ohun tí kò ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n ní àpapọ̀, wọ́n ń ṣamọ̀nà sí ohun kan tí ó nítumọ̀ tí o lè lò láti yin Ọlọ́run lógo. 

A rí èyí nínú ìwé Ẹ́sítérì, tí o sọ ìtàn obìnrin Júù kan tó wà ní ipò àrà ọ̀tọ̀ láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ là lọ́wọ́ ìpakúpa ẹlẹ́yàmẹ̀yà. Pàápàá gẹ́gẹ́bí ìyàwó àti ayaba ti Ọba Persia, kò rí ara rẹ̀ bí ẹni tí ó dára jù tàbí pàtàkì sí ètò Ọlọ́run ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. Ó kàn ń ṣe ohun tí ó dára jùlọ láti yè. Ṣùgbọ́n nítorí ẹni tí ó jẹ́, ibi tí ó ń gbé, àkókò tí ó wà, ẹni tí ó ní ipa pẹ̀lú, àti ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún un, ó lòó láti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là lọ́wọ́ ikú.

Kò sí ìbéèrè pé Ọlọ́run ti fún ọ ní ọgbọ́n, àwọn tálẹ́ńtì, ẹ̀kọ́, agbára owó, ipò, tàbí ipa tí ó ṣe pàtàkì fún ọ. Ìbéèrè náà ni báwo ni ìwọ yóò ṣe lò. O kò ní láti wà nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ láì ṣiṣẹ́ láti ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. O lè ṣíṣe fún Ọlọ́run ní ibi tí o tí ń ṣòwò tàbí ní inú ilé, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ tàbí pẹ̀lú àwọn díẹ̀. Púpọ̀ nínú wa kìí yóò jẹ́ olókìkí, ṣùgbọ́n gbogbo wa ni àwọn ènìyàn tí o wà ní àyíká àti àwọn ẹ̀bùn tí ó dá dúró tí àwọn tí ó wà ní àyíká wá ní lò. 

Lo àkókò dí ẹ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ohun gbogbo tí Ó fún ọ — gbogbo àwọn agbára, àwọn ìwà, àwọn ẹ̀kọ́, ipa, àti àwọn ìpèsè tí ó ṣe pàtàkì fún ọ. Bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ láti fi hàn ọ́ bí àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyẹn ṣe ṣe déédéé fún ọ ní ìyà sọ́ tò fún ìdí rẹ àti bí ó ṣe le lò wọ́n láti yí àwọn ìgbésí ayé àwọn mìíràn àti ayérayé padà ní ọdún yíì. Gbígbé nínú ìpè yín àti sísìn àwọn ẹlòmíràn yíò ṣe amọ̀nà fún ọdún tí ó kún fún ìtẹ́lọ́rùn. 

A gbàdúrà pé kí Ọlọ́run lo ẹ̀tọ́ yìí láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ọkàn rẹ.
Wò yíká fún àwọn ètò Bíbélì míràn tí ó ń yí Ìgbésí ayé padà
Kọ́ ẹ̀kọ́ dí ẹ̀ sí nípa Iṣẹ́ ìránṣẹ́ Àwọn Obìnrin tí a ti Yípadà (Changed Women's Ministries) 

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Living Changed: In the New Year

Ọdún Tuntun kọ̀ọ̀kan máa ń fún ni ní àǹfàní tuntun láti bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀tun. Má ṣe jẹ́ kí ọdún yìí rí bíi ti àtẹ̀yìnwá pẹ̀lú àwọn ìpinnu tí o kò ní mú ṣẹ. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yóò ràn ọ́ l'ọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ yóò sì fún ọ ní ìwòye tuntun kí o baà lè sọ ọdún yìí di ọdún tí ó dára jù lọ fún ọ.

More

A fé dúpẹ́ l'ọ́wọ́ Changed Women's Ministries fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí'wájú síi, ẹ ṣe ìbẹ̀wò http://www.changedokc.com