Gbígbẹ́ Ayé Ọ̀tun: Ní Ọdún TuntunÀpẹrẹ

Gbígbé Inú Ọdún Ní Ìjọ̀wọ́
Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún jẹ́ àkókò tí ó dára jùlọ láti dá ara ró kí á sì ronú jinlẹ̀ - kìí ṣe pé kí á lè mọ àwọn ìdí tí ó fi yẹ kí á dúpẹ́ nìkan, ṣùgbọ́n kí á tún lè rí ìmúláradá kí á sì lè dàgbà sii ní ọdún tí ó ń bọ̀.
Bí a ṣe ń ronú jinlẹ̀, a lè rán wa létí àwọn ìmọ̀lára ìbànújẹ́. Dípò kí á pa àwọn ìmọ̀lára yẹn mọ́lẹ̀ tàbí kí á jẹ́ kí wọ́n dá ìkorò sílẹ̀, a lè yan òmìnira ti ìdáríjì pè fún. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ sí ìdáríjì sì ni ìjọ̀wọ́ ara ẹni.
"Ìjọ̀wọ́" lè jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí ó máa ń mú kí àwọn ènìyàn fẹ́ lọ́ kọ́kọ́, pàápàá ní ìgbà tí ó bá ní ṣe pẹ̀lú ìdáríjì. A máa ń fẹ́ fi wé pípàdánù ogun - jíju àsìá funfun sókè láti fi ààyè gba ọ̀tá kí ó bo rí wa. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí a bá jọ̀wọ́ ara wa fún Ọlọ́run, a lè wò ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀.
Pẹ̀lú Ọlọ́run, ìjọ̀wọ́ túmọ̀ sí pé kí á nà tán pẹ̀lú ayé wa - kódà a ò ní fi ọgbẹ́ àti ẹ̀dùn wa pamọ́ fún Ọlọ́run kí ó baà lè wò wá sàn kúrò nínú wọn. Ó kún fún ìfẹ́ àti àánú fún olúkúlùkù wa. Kò nílò kí á bẹ̀rù láti fi ìrora wa fún Ọlọ́run nítorí pé a lè fi ọkàn tán An pé yóò ṣe é jẹ́jẹ́, yóò sì fi ọ̀nà pẹ̀lẹ́ yanjú ohun tí ó jẹ mọ́ ọkàn wa.
A tún lè gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run láti ṣe òdodo. Kìí ṣe nnkan àjèjì pé kí a fẹ́ rí kí ènìyàn kó èrè ohun tí ó bá ṣe. Ọlọ́run pàápàá ní ìbínú mímọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣe ìdájọ́ òdodo. Ṣùgbọ́n a ní láti gbà wípé Ọlọ́run nìkan ni ó mọ ọkàn ènìyàn. Kò sí ní ìkáwọ́ wa bóyá ẹnìkan gba ìjìyà tàbí oore ọ̀fẹ́, dídúró lórí pé a fẹ́ gba ẹ̀san yóò kàn kún wa pẹ̀lú ìkórò ni.
Tí a bá fẹ gbé ní àlàáfíà ní ọdún yìí, á ní láti fí ìbínú àti ìgbéraga wa fún Ọlọ́run, kí á ṣe àkíyèsí ọkàn ara wa. A ní láti mọ̀ọ́mọ̀ pinnu láti fi ìrora wa àti ìfẹ́ láti jẹ gàba lélẹ̀ ní ẹsẹ̀ Rẹ̀ kí á sì bẹ Ọlọ́run pé kí ó ṣẹ́ oun kan nínú wa. A ní láti gbà pé a nílò ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Krístì, ìdáríjì jẹ́ nnkan tí à ń ṣe ní ojoojúmọ́ - nígbà tí kò wù wá láti ṣe bẹ́ẹ̀ pàápáà. Nígbà míràn tí a bá ń ṣiṣẹ́ tọ ipasẹ̀ ìdáríjì, ó ṣeéṣe kí á ma jọ̀wọ́ ìrora kan náà fún Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà. Nígbà tí àwọn ògbólógbò ìmọ̀lára bá ru sókè, a máa ń dáríjì léraléra títí tí kò fi ní bí wa nínú mọ́. Pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, gbogbo nnkan ni ó ṣeé dáríjì.
Báyìí, ìdáríjì kò túmọ̀ sí pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ dára. Kò túmọ̀ sí pé kí á gba àwọn ènìyàn láàyè láti tẹ̀síwájú láti máa pa wá lára. Kìí sì í ṣe dandan pé kí á jíròrò ní ojúkorojú - kò tilẹ̀ nílò pé kí onítọ̀hún ṣì wà láàyè kí á tó dáríjì wọ́n nítórí kìí ṣe nítorí tiwọn. Ó jẹ́ ìfọwọ́sí àkókò kan tí ó wà láàrin àwa àti Ọlọ́run nìkan. Ó jẹ́ pípè É wọlé kí Ó lè wo ọkàn wa sàn.
Má ṣe gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀dùn èṣí wọ inú ọdún tuntun. Tí ohun kan bá wà tí ó yẹ kí o dárí jì, ya àkókò sí ọ̀tọ̀ láti gba àdúrà kí o sì jọ̀wọ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run. Sọ fún Un pé o nílò ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ àti pé o ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọ́n àyọrísí Rẹ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ọdún Tuntun kọ̀ọ̀kan máa ń fún ni ní àǹfàní tuntun láti bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀tun. Má ṣe jẹ́ kí ọdún yìí rí bíi ti àtẹ̀yìnwá pẹ̀lú àwọn ìpinnu tí o kò ní mú ṣẹ. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yóò ràn ọ́ l'ọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ yóò sì fún ọ ní ìwòye tuntun kí o baà lè sọ ọdún yìí di ọdún tí ó dára jù lọ fún ọ.
More









