Gbígbẹ́ Ayé Ọ̀tun: Ní Ọdún TuntunÀpẹrẹ

Ọdún Tuntun, Àkọlé Tuntun
Ní ọ́dọọdún ni a máà ń kó làálàá bò wà lórí àwọn ohun ìmúlò ni kíákíá àti ìtani-lólobó láti di "ẹ̀dá ọ̀tun" nínú ọdún tuntun. Ó lè jẹ ki ó súni bí a ṣe ń gbìyànjú láti ṣe ìsọdọ̀tun ara wa ni gbogbo oṣù kini ọdún láti wá ní ìbámu pẹ̀lú nǹkan tí àgbáyé ro wípé ó yẹ kí a jẹ. Ìgbìyànjú àti ìtiraka wá ṣọ̀wọ́n láti jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà tàbí mímú wá sí ìmúṣẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, àwọn ènìyàn máà ń fún wa ní àkọlé tuntun tí ó ń mú wá béèrè síwájú sí irú ẹni tí a jẹ.
Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ràn àkọlé. Ìdí ni pé àkọlé jẹ tajá-tẹran, ó ní ìhámọ́, bẹ́ẹ̀ ni kìí sí ṣe rẹ́gí. Wọ́n wá pẹ̀lú àwọn àròsínú, tí ó lè lòdì púpọ̀, wọ́n sì ń ṣe àfihàn àwọn àléébù wa tó burú jùlọ tàbí àṣìṣe tó ga jùlọ. Àwọn àkọlé kí ì fí àyè silẹ fún ìyàtọ̀, ìdàgbàsókè, tàbí ìràpadà.
Gbogbo wa ló ńlo àkọlé, bóyá a nifẹ sí àwọn àkọlé tí àwọn míràn fún wa tàbí èyí tí a fún ara wa. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ní a gbà àwọn àkọlé wọ̀n yẹn láyè láti fi ṣe ìdiwọ̀n fún wa kí wọ́n sì sọ fún wa pé a kò tó nǹkan. Ó kàn. Á ṣe àfikún kékeré yìí, síbẹ̀ náà ó jẹ ọ̀rọ̀ tí ó ṣe pàtàkì nígbàtí a bá ń ṣe àpèjúwe ara wa ti a si gbà àwọn àkọlé wọ̀nyí láyè láti sọ wa di ẹni tí kò yẹ. Bóyá ó ti gbọ́ tí àìníye ènìyàn tí sọ bẹ́ẹ̀, tàbí kí ìwọ náà tí sọ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. “Èmi kan jẹ́ ọmọ ilé ìwé gíga ni” tàbí “mo kan jẹ́ ẹnití ó kúndùn nǹkan”
Òtítọ́ ibẹ̀ ni wípé o kìí ìṣe ọjọ́ orí rẹ, ipò iṣẹ́ rẹ, ìwádìí àìsàn rẹ, ipò ìgbéyàwó rẹ, itiraka rẹ, tàbí ọjọ́ àná rẹ. Àwọn àkọlé wọ̀nyẹn lè jẹ àpèjúwe ipò rẹ, ìgbà rẹ, tàbí ìdánwò rẹ, ṣùgbọ́n ìdánimọ̀ rẹ tòótọ́ wá nínú ẹniti Ọlọ́run sọ pé ó jẹ́ kò sí nkan míràn lẹ́yìn èyí
O lẹ́wà, o jẹ́ akọni, o sì jẹ àmúyangàn. A ti sọ ọ́ di ọ̀tun nínú Kristi. A kò fún ọ ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bíkòṣe tí agbára àti ti ìfẹ́, àti ti ọkàn tí ó yè kooro. Ó jú aṣẹ́gun lọ nínú Krístì tí ó ń fún ọ ní agbára. A kanlẹ̀ dá ọ ni fún ìdí kan. O jẹ́ àyànfẹ́. Ó jẹ́ ẹnití a yàn. Ó sì kún ojú òṣùwọ̀n
Rònu lórí àwọn àkọlé tí ó ti ń lò láti ọdún tí ó kọjá àti láti ìgbé ayé rẹ. Bí i mélòó ni o ti ṣe àmúlò rẹ̀ tí ó lòdì sí nǹkan ti Ọlọ́run sọ nípa rẹ nínú Bíbélì? Ṣé àwárí àwọn apá ibi tí ìgbé ayé rẹ tí jẹ kò ní ìmọ̀lára ìtìjú, àìláàbò, tàbí ẹrú dé tí àwọn ènìyàn lè rí. Béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti ṣe àfihàn àwọn àkọlé tí ó ń di ẹrù wúwo rù ọ́ kí ó sì béèrè fún iranlọwọ láti dínkù. Gbá Ọlọ́run láyè láti rán ọ lọ́wọ́ láti jẹ́kí idanimo rẹ kì ó wà ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́ inú Bíbélì kí ó bàa lè gbé nínú ọdún yí, ní àkọ́kọ́ àti ṣáájú, gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run.
Nípa Ìpèsè yìí

Ọdún Tuntun kọ̀ọ̀kan máa ń fún ni ní àǹfàní tuntun láti bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀tun. Má ṣe jẹ́ kí ọdún yìí rí bíi ti àtẹ̀yìnwá pẹ̀lú àwọn ìpinnu tí o kò ní mú ṣẹ. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yóò ràn ọ́ l'ọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ yóò sì fún ọ ní ìwòye tuntun kí o baà lè sọ ọdún yìí di ọdún tí ó dára jù lọ fún ọ.
More