Bí A (Kò) Ṣe Lè Gba Ayé Là: Òtítọ́ Nípa Fífi Ìfẹ́ Ọlọ́run Hàn Sí Àwọn Ènìyàn Tí Ó Wà Ní Ẹ̀gbẹ́ẹ̀ RẹÀpẹrẹ

How (Not) to Save the World: The Truth About Revealing God’s Love to the People Right Next to You

Ọjọ́ 4 nínú 5

Bí A (Kò) Ṣe Le Gba Ayé Là: Gbé láti wu Ènìyàn

Ní ìgbà tí ìyá mi wà ní ọdún 50 sókè, ó bẹ̀rẹ̀ ìṣe kejì rẹ̀. Ó ti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìránsẹ́ òpópónà fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún pẹ̀lú ìgbòkègbodò ìdílé wa ó sì ní ohùn ọlá àṣẹ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ó ń sìn. Síbẹ̀síbẹ̀ ó jìjàkadì pẹ̀lú bóyá Ọlọ́run ń pèé ni báyìí sí ńkan titun. Kí ni yóò túmọ̀ sí fún un, ní ìpele ìgbésí ayé rẹ̀ yìí, láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tuntun tí Ọlọ́run ní fún un? Ṣé ó pẹ́ jù láti ṣe ìyípadà? Ǹ jẹ́ ó ní ìgboyà láti bọ́ sínu ìpè tuntun

Mo gbìyànjú láti fi etí sí àwọn ìbẹ̀rù rẹ̀ àti láti ṣe ìwádìí ohun tí ó ru sókè nínú ọkàn rẹ̀ láti jẹ́ kí ó jáde. Ní ìkẹyìn ó jẹ́wọ́, pẹ̀lú èémí iderun, “Mo fẹ́ jẹ́ olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.” Ìyá mi ti ní ìrẹ̀wẹ̀sì nípasẹ̀ àwọn ìbẹ̀rù rẹ̀ nípa ohun tí ènìyàn yóò sọ, àti bíí yóò ṣe rí láti gbìyànjú láti ṣe ńǹkan tuntun ní àkókò ìgbésí ayé rẹ̀.

Gbogbo wa ti rò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò pé a kò ní àwọn ohun àmúyẹ̀ láti ṣe àwọn ohun tí Ọlọ́run ń pè wá láti ṣe. A yọ ara wa kúrò ní àwọn ipò tàbí àwọn ipa nítorí àwọn ìlàkalẹ̀, àwọn èrò, tàbí àwọn ìrètí àwọn ènìyàn mìíràn. Báwo ni a ṣe lè wà ní ààyè fún Jésù kí a sì fi Jésù hàn ayé bí a bá ń gbìyànjú ní ìgbà gbogbo láti wu ayé tí Jésù wá láti gbà là? Gbígbé láti wu ènìyàn ni (kìí ṣe) láti gba ayé là.

Bí a bá jẹ́ ẹrú ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ, ní ìgbà náà a kò lè gbọ́ràn sí ohun tí Ọlọ́run ń sọ. A kò lè gbé ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́ tí Ọlọ́run ń pè wá láti gbé ní ìgbà tí a bá ń gbìyànjú láti jẹ́ kí gbogbo ènìyàn mìíràn dunnú sí gbogbo ìgbésẹ̀ wa. Tí o bá ń gbé láti wu ènìyàn, tí kò sìí ṣe láti wu Ọlọ́run, ìwọ kìí yóò lè bọ́ sínú èrè ìdí kíkún tí Ọlọ́run ní fún ìgbésí ayé rẹ. Àwọn ènìyàn kìí yóò mọ Jésù tí a bá ń gbé láti wu àwọn ènìyàn tí Jésù wá láti gbàlà.

Ìyá mi ti jẹ́ olùkọ́ ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní báyìí fún ọdún díẹ̀. Ó ń gbé ní ìgbà òtun ti ìgbésí ayé rẹ̀, ó sọ fún mi, “Èyí ni ohun tí ó yẹ kí n máa ṣe. Mo mọ̀ pé ibi yìí ló ye kí n wà.” Ọ̀rẹ́ mi, gbàgbé ipó tí o wà tẹ́lẹ̀. Ya àwọn ìgbà àìfojúrí fún ohun tí ó yẹ kí o ṣe àti ní ìgbà tí ó yẹ kí o ṣe é. Mú àwọn gbèdéke ti ara rẹ kúrò. Mú àwọn gbèdéke kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ńkànkan tí ó yàtọ̀ tí Ọlọ́run fẹ́ láti ṣe nínú wa àti nípasẹ̀ wa ní gbogbo àkókò ayé wa. Máṣe yára. Máṣe fojú rẹ. Ní àkókò yìí tí o ń gbé báyi, Ọlọ́run ní ohun kan pàtó fún ọ láti dì mú àti ohun kan pàtó fún ọ láti fún.


RmDáhùn

Kíni ohun tí ó fún ọ ní ìrẹ̀wẹ̀sì láti tẹ̀lé ìtara àti ìpè tí Ọlọ́run ní fún ọ?

Kíni ó jẹ́ ewu tí a bá gbé láti tẹ̀lé àṣà, tàbí gbé láti wu ènìyàn dípò Ọlọ́run?

Kíni ńǹkan tí o lérò pé Ọlọ́run ń pè ọ́ sí tí o lè sọ bẹ́ẹ̀ni sí ní òní?


Nípa Ìpèsè yìí

How (Not) to Save the World: The Truth About Revealing God’s Love to the People Right Next to You

Ṣé o fẹ́ jà fún àwọn ènìyàn tí o fẹ́ràn kí o sì fi han àwọn ẹlòmíràn bí wọ́n ṣe ní iye l'órí tó sí Ọlọ́run? Nínú ètò kíkà ọlọ́jọ́ 5 yìí, tí ó dá l'órí ìwé Hosanna Wong How (Not) to Save the World, ṣe àwárí àwọn irọ́ tí ó ń dí ọ l'ọ́wọ́ l'áti ní ìfẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn bí Ọlọ́run ṣe pè ọ́ sí. Gba àkókò l'áti ṣe àwárí ìfìwépè Jésù l'áti mọ̀ On, kí o pín-In pẹ̀lú áwọn ẹlòmíràn nípasẹ ìrírí aláìlẹ́gbẹ́ rẹ.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ HarperCollins/Zondervan/Thomas Nelson fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ ṣe àbẹ̀wò: https://bit.ly/savetheworldyouversion