Ọ̀nà Ìjọba náàÀpẹrẹ

The Way of the Kingdom

Ọjọ́ 3 nínú 5

Àríyànjiyàn Kò Ṣeé Dènà

Gbogbo ohun tí Ọlọ́run bá ṣe ni ó máa ń rí àtakò láti ọ̀dọ̀ ọ̀tá. Kò sí ìgbàgbọ́ tí kò ní àtakò. Kò sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bíi àtùnjí láì sí àtakò. Ìmúpadàbọ̀sípò máa ń yí ipò nǹkan padà, ó sì máa ń tú àṣírí àwọn iṣẹ́ òkùnkùn tí ó wà nínú ìgbésí ayé àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ ènìyàn, àwọn ìjọba àti àwọn orílẹ̀-èdè. Ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ọ̀nà àlàfo. Kò sí ẹni tí ó lè fi ẹsẹ̀ kan gbé ayé kí ó sì tún fi ẹsẹ̀ kan gbé Ìjọba náà ní èẹ̀kan náà. Ọba Ìjọba náà ń wá bí yóò ṣe máa gba òkùnkùn ní ọwọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n rẹ̀, ní ìgbà tí Èṣù ń wá bí yóò ṣe máa dá Òun dúró kí ó sì mú kí òkùnkùn náà pọ̀ sí i.

Jésù sọ fún wa pé ẹni tí ó kéré jùlọ nínú ìjọba Ọlọ́run tóbi ju Jòhánù Oníbatisí lọ (wo Mátíù 11:11). Kí ni èyí túmọ̀ sí? Jésù ń sọ wí pé a ní agbára àti àṣẹ gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Ọlọ́run nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, ṣùgbọ́n Ó tún kìlọ̀ fún wa wí pé ìjà kò ṣeé yẹra fún. Ní igbà tí Ìjọba náà bá dé, yóò dá ìjọba tuntun kan sílẹ̀, yóò sì dá àwọn ènìyàn tuntun kan tí wọ́n wà nínú májẹ̀mú, tí wọ́n á sì wà ní abẹ́ Ọba tuntun kan.

Jésù mọ̀ pé gbígbé ìgbésí ayé òdodo nínú ayé tí ìwà ibi àti òkùnkùn ti gba òde kan túmọ̀ sí gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìṣèlú àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀. Ó máa yọrí sí inúnibíni. Ní ìgbà tí Jésù sọ fún wa pé Ìjọba Ọlọ́run ń jìyà ìwà ipá (wo Mátíù 11:12), Ó ń jẹ́ kí a mọ irú ìgbésẹ̀ àti ìdáhùn tí a yíò máa ṣe. A rí àpẹẹrẹ yìí nínú Ìwé Mímọ́. Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésẹ̀, àwọn ọ̀tá sì bẹ̀rẹ̀ sí ta ko ohun tí Ọlọ́run ń ṣe. Ó ti wà báyìí láti ìbẹ̀rẹ̀.

Ìkórìíra á máa bá a nìṣó títí tí Ìjọba Ọlọ́run á fi dé. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, irú-ọmọ obìnrin náà - Jésù Kristi - àti gbogbo àwọn tí ó wà nínú Kristi ni yóò borí. Kí ó tó di ìgbà yẹn, Ìjọba Ọlọ́run á máa tẹ̀ síwájú ní ọ̀nà tí ó kàmàmà.

A gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí Jésù ṣe nípa fífi Ìhìn Rere náà hàn àti fífi òkùnkùn rẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ ni o, a kò lè yẹra fún aáwọ̀. Àmọ́, ó dájú pé a máa ṣẹ́gun.


Nípa Ìpèsè yìí

The Way of the Kingdom

Ọlọ́run ń sọ ìjọ Rẹ̀ jí, a sì ní láti rí àkópọ̀ ìṣe Rẹ̀ yìí. Ní ìgbà tí ǹǹkan bá nira, ó maá ń ṣe wá bíi kí a j'áwọ́. Ẹ̀wẹ̀, ìgbà yìí kìí ṣe àsìkò tí a lè j'áwọ́. Da ara pọ̀ mọ́ wa bí a ó ṣe máa kà nípa àsìkò tí a wà, àti bí a ó ṣe mọ àwọn ìgbésẹ̀ tí a ó gbé láti dúró kí a sì mú Ìjọba Ọlọ́run gbòòro sí í.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ilé-iṣẹ́ Ìtẹ̀wé Baker fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: http://bakerpublishinggroup.com/books/the-way-of-the-kingdom/395661