Ọ̀nà Ìjọba náàÀpẹrẹ

Ǹjẹ́ O ní Ohun Ìkọ̀sẹ̀?
Jòhánù Onítẹ̀bọmi ti lo gbogbo ìgbésí-ayé àgbà rẹ̀ láti kéde bíbọ̀ Mèsáyà. Jòhánù jẹ́ ìbátan Jésú, èyí túmọ̀ sí pé àwọn méjèèjì mọ ìyànu tí ó rọ̀gbà yí ìbí wọn ká. Ní báyìí, wọ́n ti ti ara bọ iṣẹ́ ìránṣẹ́ oníkálukú wọn, àti Jésù àti Jòhánú ń kéde t'ìgboyàtìgboyà wípé Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀. Wọ́n jọ fi ìmọ̀ ṣe ọ̀kan lórí èyí.
Láìrò tẹ́lẹ̀, ẹ̀wẹ̀, Jòhánù rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti lọ bi Jésù bóyá Òun ní Mèsáyà tàbí kí wọ́n wá ẹlòmíràn. Ǹjẹ́ Jòhánù kò mọ̀ ni? Ó dájú pé ó mọ̀. Ní báyìí, inú rẹ̀ pò pọ̀.
Jòhánù ń retí afipágbàjọba tí yìó yí àwọn ìlànà òṣèlú, ẹ̀sìn àti àṣà ọjọ́ rẹ̀ padà. Ó gbàgbọ́ pé Mèsáyà yíó gbé sùnmọ̀mí òdodo tí Ọlọ́run tì lẹ́yìn dìde. Síbẹ̀ nibo ni Jòhánù wà lọ́wọ́lọ́wọ́? Ó wà nínú ìdè ipá lọ́wọ́ aláìṣòtítọ́ àti abọ̀rìṣà Hẹ́rọ́dù. Kíni Jésù ń ṣe nípa rẹ̀? Kò sí ohun kan.
Bí Jésù bá ní Ẹni tí ń bọ̀, ǹjẹ́ kò níi máa ṣe àgbékalẹ̀ Ìjọba tirẹ̀, kí ó gbé ìgbésẹ̀ láti dà ojú àwọn aninilára olóṣèlú bo ilẹ̀, kí ó pè fún àtúnṣe láàrin àwọn ẹlẹ́sìn jàǹkànjàǹkàn, kí ó sì fí ìdí ara rẹ̀ múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olóòótọ́ àti Ọba tí a yàn láti ọ̀run wa? Ǹjẹ́ kò níí dóòlà ipò tí Jòhánù wà nínú túbú, ní ìgbà tí ó jẹ́ pé yío mú ìdájọ́ òdodo oníná rẹ̀ wá sí orí àìṣòdodo gbogbo? Ní ìwòye ti Jòhánú, ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí jẹ́ bẹ́ẹ̀ni.
Jésù kìlọ̀ fún Jòhánù pé kí ó má gba ohun ìkọ̀sẹ̀ láàyè. Jòhànù ní láti yàn láti máṣe bọ́ sí inú ìdẹwò, kí ó sì gbàgbọ́, kódà láìka ẹ̀gbin, àìṣòdodo àti ìpalára sí. Fún Jòhánú, kò níí sí ìdáǹdè. Ìpòǹgbẹ̀ rẹ̀ tí ó ń b'ani nínú jẹ́ sọ ọ́ di aláìmọ̀kan, oníyèméjì àti aláìgbàgbọ́. Nínú gbogbo ìrírí àti àwọn ipò yìí Jésù pè é láti ní ìgbàgbọ́.
Ìgbà mélòó ni ó jẹ́ pé bí a bá ti rí ìjákulẹ̀ tàbí à ń rí àwọn àtakò kọ̀ọ̀kan àti àìṣòdodo, a máa ń kọsẹ̀ lára Ọlọ́run? A ó bẹ̀rẹ̀ síi ṣe iyèméjì nípa ìfẹ́ Rẹ̀, dídára Rẹ̀, jíjẹ́ olóòótọ́ Rẹ̀, ìwàláàyè Rẹ̀ àti bí ó bá tilẹ̀ wà gan an. Àwọn mélòó ní wọ́n ti yí padà tí wọn kò tẹ̀lé Jésù mọ́ látàrí ohun kannáà yìí? Báyìí ni ọ̀tá ṣe máa ń pa iná Ẹ̀mí.
A ṣe kòǹgẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run mìíràn báyìí. Bí a bá fẹ́ rìn ní ọ̀nà Ìjọba ọ̀run kí a sì dá ara pọ̀ mọ́ Ọlọ́run nínú ìṣe ọwọ́ agbára Rẹ̀ ní ìràn tiwa yìí, a kò gbọdọ̀ ní ohun ìkọ̀sẹ̀.
Nípa Ìpèsè yìí

Ọlọ́run ń sọ ìjọ Rẹ̀ jí, a sì ní láti rí àkópọ̀ ìṣe Rẹ̀ yìí. Ní ìgbà tí ǹǹkan bá nira, ó maá ń ṣe wá bíi kí a j'áwọ́. Ẹ̀wẹ̀, ìgbà yìí kìí ṣe àsìkò tí a lè j'áwọ́. Da ara pọ̀ mọ́ wa bí a ó ṣe máa kà nípa àsìkò tí a wà, àti bí a ó ṣe mọ àwọn ìgbésẹ̀ tí a ó gbé láti dúró kí a sì mú Ìjọba Ọlọ́run gbòòro sí í.
More