Ọ̀nà Ìjọba náàÀpẹrẹ

Níní Etí Láti Gbọ́
Ọ̀nà tí ó jà jù láti fi ìtàn, Ìwé Mímọ́ àti àṣà orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì ṣọwọ́ sí àrọ́mọ-dọ́mọ ní àrọ́bá. Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ní onírúurú ọ̀nà àti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà nípasẹ̀ àwọn wòlíì. Ọlọ́run nílò àwọn ènìyàn tí ń gbọ́ ohùn Rẹ̀ tí wọ́n sì ń gbé ìgbésí ayé wọn nípasẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń tí ẹnu Rẹ̀ jáde. Níní etí láti gbọ́ ṣe pàtàkì gan ní ìgbà ayé Jésù.
Nígbà tí Ó bá sọ̀rọ̀, àkókò tó láti tẹ́ etí sílẹ̀ àti láti ní òye nìyẹn. Bíbélì fi yé wa wípé títẹ́ etí sílẹ̀ jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ àti jíjẹ́ olóòótọ́. Etí láti gbọ́ jẹ́ àkànlò èdè tí ń pè ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ṣí ọkàn rẹ̀ payá sí ohùn tí à fẹ́ fì hàn án. Ní ìdàkejì, sísọ wípé “Ẹni tí ó bá létí láti gbọ́ràn, jẹ́kí ó gbọ́,” jẹ́ ǹkan kan náà pẹ̀lú, “Jí kúrò nínú àsùnpiyè kí o sì ṣe àkíyèsí!” Àkíyèsí ohun tì ẹ̀mí ni ó lè fún wa ní òye nípa ìfihàn ti ẹ̀mí.
Ènìyàn mélòó ni ó ti kùnà láti ṣe àkíyèsí ìwàláàyè Ọlọ́run nítorí wọn kò nání wọn kò sì ní òye ohun tí Ọlọ́run ńṣe? Wọn ṣe àyà wọn le kàkà kí wọn síi payá. Kàkà kí wọ́n yí padà, ní ṣeni wọ́n ń bu ẹnu àtẹ́ láti dáàbò bo ìpinnu tí wọ́n ti ṣe. Àkókò tó fún wa láti jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀ tí ó ní ète tí ó sì ní etí láti gbọ́. A kò lè máa sin àṣà àti òṣèlú pẹ̀lú ìrètí wípé a máa dé Ìjọba ọ̀run. Àwọn àtúntò, ìyípadà òjijì àti ìdàrúdàpọ̀ lè mú àwọn àǹfààní tí a kò tilẹ̀ lérò dé bá ìṣe ìdàgbàsókè Ìjọba Ọlọ́run ó sì lè ru àwọn ìlànà ìṣẹ̀dá ìṣúná, okòwò, òṣèlú, ẹbí, ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ìjọba Ọlọ́run. A máa kojú ìtakò tí a máa ní láti borí kí a tó lè jẹ àwọn àǹfààní tó tẹ̀lé ẹ.
Ara Kristi náà gbúdọ̀ jí gìrì sí àwọn àǹfààní tí ma ń yọjú lákòókò ìrúkèrúdò. A gbúdọ̀ ríran kí a sì gbọ́ pẹ̀lú òye titun, àti wípé a gbúdọ̀ gba ìpọ́njú láàyè láti ru ìlànà ìṣẹ̀dá sókè fún ìdàgbàsókè Ìjọba Ọlọ́run. Kí á gba Ẹ̀mí náà láàyè láti ní ipa lára ìrètí wa àti kí ìrísí wa le wà ní ìbámu pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run fún ìran tiwa.
Nípa Ìpèsè yìí

Ọlọ́run ń sọ ìjọ Rẹ̀ jí, a sì ní láti rí àkópọ̀ ìṣe Rẹ̀ yìí. Ní ìgbà tí ǹǹkan bá nira, ó maá ń ṣe wá bíi kí a j'áwọ́. Ẹ̀wẹ̀, ìgbà yìí kìí ṣe àsìkò tí a lè j'áwọ́. Da ara pọ̀ mọ́ wa bí a ó ṣe máa kà nípa àsìkò tí a wà, àti bí a ó ṣe mọ àwọn ìgbésẹ̀ tí a ó gbé láti dúró kí a sì mú Ìjọba Ọlọ́run gbòòro sí í.
More