Ibi Tí Àdúrà Ti Ń DájúÀpẹrẹ

Where Prayer Becomes Real

Ọjọ́ 5 nínú 5

Ọjọ́ Karùn-ún

Olúwa wà Ní Tòsí 

Fún èyí tí ó pọ̀ jù lọ ní inú ìgbésí ayé Kristiẹni mi, mi ò mọ̀ pé mò ń bá ara mi jà nínú ádùrá. Ní ìgbà tí mo kùnà láti "gba àdúrà dáadáa" nípasẹ ìlànà mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọjú ìjà sí ara mi kí n lè túbọ̀ gbìyànjú, kí n sì fi hàn pé mo jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n mò ń gbìyànjú láti máa gba àdúrà tọkàntọkàn ní inú ẹran ara mi, dípò kí n máa wá òtítọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún mi. Ní ìsàlè ọkàn mi, mi ò gba pé Ọlọ́run fẹ́ ìṣòtítọ́.

Ní inú Orin Dáfídì 145:18 a gbọ́ ìdàkejì èyì: "Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́." Bí ọ̀pọ̀ nínú wa ṣe ń kọ́ ẹ̀kọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé pé a lè mú Ọlọ́run wá sí inú ìjàkadì wa, ẹ̀ṣẹ̀ wa àti ìdùnnú wa, ẹ jẹ́ kí n sọ pé ọ̀pọ̀ nínú wa ṣì ń kùnà láti mú Ọlọ́run sí inú ádùrá wa. A máa ń gba àdúrà sí Ọlọ́run, dípò kí a mọ̀ pé Ó wà níbè ní ìgbà tí a bà ń gba àdúrà (tàbí tí a kùnà ní inú ádùrá). Ní ìgbà tí mo bá ronú nípa àdúrà, mo máa ń ronú pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi, ó ń pè mí pé kí n mú ohun tí mò ń ṣe yìí wá sí ọ̀dọ̀ òun. Ní ìgbà tí oorun bá gbé mi, màá bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọ́run má ṣe jẹ́ kí n sùn, àmọ́ mi ò kí ń fí rírẹ̀ ara sí inú àdúrà.

Olùdarí mi ni ó kọ́kọ́ sọ fún mi pé àdúrà kì í ṣe ibi tí ènìyàn ti lè ṣe dáadáa, bí kò ṣe ibi tí ènìyàn ti lè jẹ́ olóòótọ́. Ibẹ̀ ni àdúrà ti wá sí ìyè, nítorí mo rí pé Ọlọ́run fẹ́ bá mi pàdé ní inú àwọn ìfẹ́ ọkàn mi tí ó jinlẹ̀ jù lọ, àwọn ìṣòro mi àti ìdààmú tí mo ní ní inú àjọṣe mi pẹ̀lú rẹ̀. Àwọn ìkésíní wọ̀nyí kì í ṣe èyí tí kò bá òfin mu rárá, se ni wọ́n jẹ́ ìkésíni láti mọ̀ nípa ìwàláàyè Rẹ̀ kí n sì rí àánú Rẹ̀ gbà, ní àkókò tí mo nílò rẹ̀ gan-an. 

Mo wá rí i pé ọ̀pọ̀ àdúrà tí mò ń gbà kì í ṣe òótọ́, torí pé bí mo ṣe rò pé Kristẹni olóòótọ kan á ṣe ni mo ṣe ń gba àdúrà. Nítorí náà, ìgbésí ayé ádùrá mi di ìgbésí ayé tí mò ń ṣe bíi pé mo wà, mo ní ìrètí pé bí mo bá pidán fún àkókó gígùn, màá di ẹni tí ó mọ nǹkan ṣe dáadáa. Ṣùgbọ́n èyí kò yọrí sí nǹkan kan. Ní òtítọ, ó mú kí n jáwọ́ ní inú ádùrá gbígbà. Ní ìgbà tí mo rí ìkésíni Ọlọ́run láti mọ ìfẹ́ rẹ̀, àti láti mọ ìwàláàyè Rẹ̀ nínú òtítọ́, mo rí ohun tí ó túmọ̀ sí wípé Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi ní àwọn ibi wọ̀nyí. Ní ẹ̀ẹ̀kan sí, àwọn òtítọ́ wọ̀nyí kì í wulẹ ṣe èyí tí a gbọ́dọ̀ gbà gbọ́, àmọ́ wọ́n jẹ́ òtítọ́ tí a gbọ́dọ̀ gbé yọ. 

Ǹjẹ́ àwọn ohun kan wà tí ó ń dà ọ́ láàmú tí ò ń gba àdúrà sí Ọlọ́run nípa rẹ̀? Àwọn ìfẹ́ ọkàn wo ni Ọlọ́run fẹ́ kí o ní ní ìgbà tí o bá wà ní iwájú rẹ̀? Báwo ni ó ṣe máa rí tí a bá ń bá Olúwa sọ wọ́n? Ǹjẹ́ o lè gbà gbọ́ pé, láti òkè dé ilẹ̀, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ ní àwọn ibi wọ̀nyí, àbí o sì ń fi àwọn apá kan ní inú ọkàn rẹ pa mọ́ fún ara rẹ?

Ẹ ṣeun fún kíkà ẹ̀kọ́ àṣàrò Bíbélì yìí. Mo gba àdúrà pé o ti ní ìbùkún nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wònyí. Tí ẹ bá fẹ́ràn ohun tí mo kọ yìí, màá fún yín látè láti ka orí kìíní ìwé mi. Ẹ lè wò ó ní https://www.whereprayerbecomesreal.com/  

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Where Prayer Becomes Real

Àdúrà ní ìgbà míràn lè dà bíi ẹni wípé o dá nìkan wà. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, nínú àdúrà, mo gbìyànjú láti mú ẹ̀mí àti ọkàn mi dákẹ́, èrò inú mi sì ń sáré káàkiri. Ní ìgbà míràn mo kàn ma sùn lọ. Àwọn ìgbà kan wà tí ó dà bíi wípé àdúrà mi máa ń ta ba òrùlé padà. Àmọ́ ohun tí a kìí sábà mọ̀ ni wípé Olúwa n fún wa ní ìròyìn rere ní àwọn ibi wọ̀nyí. Ẹ jẹ́ kí á lo àkókò díẹ̀ láti gbé ìhìn rere nípa àdúrà yẹ̀ wò.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ilé-iṣẹ́ Ìtẹ̀wé Baker fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://bakerbookhouse.com/products/235866