Ibi Tí Àdúrà Ti Ń DájúÀpẹrẹ

Where Prayer Becomes Real

Ọjọ́ 3 nínú 5

Ọjọ́ Kẹta

Gbígba Àdúrà Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́

Bí a bá ti lẹ̀ n jẹ́ri sí gbogbo ohun tí ó tọ́ nípa àdúrà, a yíò ríi wípé a ṣì ń jà fitafita ní ìgbà tí a bá ń gba àdúrà. A ṣì ń ṣe kàyéfì bóyá Ọlọ́run wà. A máa ń ké jáde, a sì sábà máa ń ní àwọn ìrírí ní inú àdúrà tí a kò mọ bí a ṣe lè túmọ̀ rẹ̀. Bí Ìwé Mímọ́ bá lè tọ́ wa sí ọ́nà ní áwọn ipò wọ̀nyí. Ó ṣeé ṣe kí ó rí bẹ́ẹ̀. 

Ní inú 1 Jòhánù 3:19-20, Jòhánù darí ọkàn wa sí irú irú ìjàkadì yìí gan-an. Ní àkọ́kọ́ a rí i wípé a wà "ní iwájú Rẹ̀" a sì tún ní láti fi ọkàn ará wa balẹ̀ ní iwájú Rẹ̀. Èyí ṣe àjèjì díẹ̀ sí wa ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀. Kí ni ìdí tí ó fi yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ ní ìgbà tí a bá wà ní iwájú Ọlọ́run? Kí ni ó dé tí mo fi ń bá ara mi sọ ọ̀rọ̀ ní ìwájú Ọlọ́run?! Ohún tí Jòhánù sọ tẹ̀lé e ṣe àlàyé ìṣòro náà: "nígbàkúùgbà tí óókan-àyà wa bá dá wa ní ẹ̀bi, Ọlọ́run tóbi ju òòkan-àyà wa lọ, Ó sì mọ ohun gbogbo." 

Kíyèsí wípé Jòhanu gbà wípé ọkàn wa lè dá wa ní ẹ̀bi ní iwájú Ọlọ́run. Mo ti mọ irú ìdálẹ́bi yìí. Mo ti tiraka pẹ̀lú irú àwọn ìṣe báwọ̀nyí ní inú ádùrá. Bíi ọ̀pọ̀ nínú wa, ní ìgbà tí mo ṣe bẹ́ẹ̀, mo ṣe nǹkan méjì lái fi iyè síi: Ní àkọ́kọ́, mo gbà wípé ìmọ̀lára mi níí ṣe pẹ̀lú ìṣe Ọlọ́run. Ní ìgbà tí mò ń dá ara mi ní ẹ̀bi, mo lérò wípé Ọlọ́run ni ó ń dá mi ní ẹ̀bi. Èkejì, dípò tí màá fi gbé ìṣòro náà tọ Ọlọ́run lọ, tí màá sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé wípé ní inú Kristi nìkan ni mo ti lè mọ ìrètí tí ó wà ní àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, níṣe ni mo yíjú sí ara mi. Mo gbà wípé mi ò gba àdúrà dáadáa, tàbí pé mi ò gba àdúrà tọkàntọkàn, tàbí pé ìgbésí ayé mi kò dára tó. Mo gbàgbé wípé Ọlọ́run mọ̀ wípé mí kò mọ̀ bí a ṣe n gba ádùrá mi, àti wípé Òun gba àdúrà fún mi. 

Ṣùgbọ́n ní ibí yìí, ṣe àkíyèsí ibi tí ìṣírí Jòhánù wà. Ọlọ́run tóbi jù lọ. Ọlọ́run mọ gbogbo rẹ̀. Ọlọ́run tóbi ju ọkàn rẹ lọ́. Jòhánù gbà wípé óókan-àyà rẹ fúnra rẹ̀ ni ó ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan, àwọn nǹkan wọ̀nyẹn kò sì sọ fún ọ nípa Ọlọ́run. Ní ìgbà tí ọkàn rẹ bá ń dá ọ ní ẹ̀bi, Jòhánù ń rán ọ létí wípé Ọlọ́run tóbi ju ọkàn rẹ lọ, ó sì ń yí ọ padà sí ara Rẹ̀. Jòhánù ràn ọ́ l'ọ́wọ́ láti rántí wípé Ọlọ́run mọ́ ohun gbogbo – pàápàá púpọ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ju ìwọ gan-an lọ – Ó sì pè ọ́ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nítorí ohun tí Ó ti ṣe ní àṣeyọrí fún ọ. Ṣùgbọ́n ìdí nìyí tí àdúrà fi jẹ́ èyí tí a fi ìgbàgbọ́ gbà ní ìgbà gbogbo. A gbọ́dọ̀ gbọ́ òtítọ́, àmọ́ a ni láti ṣe àmúlò rẹ̀ bakan náà. 

Báwo ni o ṣe ń tiraka nínú àdúrà? Kí ni ọkàn rẹ sọ fún ọ ní inú àdúrà ti o lérò wípé ti Ọlọ́run ni? Báwo ni o ṣe lè mọ̀ wípé Ọlọ́run tóbi jù lọ ní àwọn ibi wọ̀nyí? 

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Where Prayer Becomes Real

Àdúrà ní ìgbà míràn lè dà bíi ẹni wípé o dá nìkan wà. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, nínú àdúrà, mo gbìyànjú láti mú ẹ̀mí àti ọkàn mi dákẹ́, èrò inú mi sì ń sáré káàkiri. Ní ìgbà míràn mo kàn ma sùn lọ. Àwọn ìgbà kan wà tí ó dà bíi wípé àdúrà mi máa ń ta ba òrùlé padà. Àmọ́ ohun tí a kìí sábà mọ̀ ni wípé Olúwa n fún wa ní ìròyìn rere ní àwọn ibi wọ̀nyí. Ẹ jẹ́ kí á lo àkókò díẹ̀ láti gbé ìhìn rere nípa àdúrà yẹ̀ wò.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ilé-iṣẹ́ Ìtẹ̀wé Baker fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://bakerbookhouse.com/products/235866