Ibi Tí Àdúrà Ti Ń DájúÀpẹrẹ

Where Prayer Becomes Real

Ọjọ́ 1 nínú 5

Ọjọ́ Àkọ́kọ́

Gbígbọ́ Ìhìn Rere Àdúrà

Ní ìgbà tí mo bá wo ẹ̀yìn wò nípa bí àdúrà ti jẹ́ ní ìgbésí ayé mi, ó má ń rí bíi àfi ipá ṣe. Ní ìgbà tí ó yá, mo wá gbà gbọ́ pé ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ni pé kí n máa gba àdúrà dáadáa. Nítorí náà ní ìgbà tí mo bá kùnà - ní ìgbà tí èrò mi bá ń rìn gbéregbère tàbí tí mo bá sùn lọ - mo máa ń dá ara mi ní ẹ̀bi pé mi ò ṣe dáadáa, ojú á sì gbà mí tì. 

Ní inú ìṣòro ni a ti má ń mọ dídára àdúrà. Pọ́ọ̀lù sọ èyí ní inú Ìwé Rómù 8:26: "Bákan náà, Ẹ̀mí tún ń ràn wá l'ọ́wọ́ ní inú àìlera wa. Nítorí a kò mọ ohun tí ó tọ́ tí à bá máa gba àdúrà fún. Ṣùgbọ́n Ẹ̀mí fúnrarẹ̀ a máa bẹ̀bẹ̀ fún wa nipa ọ̀dọ̀ Ọlọrun ninà ọ̀tí a kò lè fi ẹnu sọ." A kò mọ àdúrà á gbà bí ó ti yẹ. Ròó, Ní ìgbà tí Ọlọ́run bá ń rò nípa agbára ìgbàdúrà rẹ, Ọlọ́run mọ̀ pé o kò mọ bí o ṣe lè gba àdúrà. Ó mọ̀. Ó ní òye. 

Ṣùgbọ́n bí a bá fi sílẹ̀ níbẹ̀, ó lè dà bíi ẹni pé ó ń bani ní inú jẹ́ díẹ̀. Ó lè fúnni ní ìṣírí, bóyá, pé Ọlọ́run fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé a kò mọ bí a ṣe ń gba àdúrà. Mò ń rí ìtùnú nínú òtítọ́ náà pé Ọlọ́run mọ̀ ọ́n ó sì ní òye rẹ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dúró sí ibi mímọ̀ nìkan. Ọlọ́run ti ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀! Nínú Hébérù 4:14-16, a sọ fún wa wípé a ní àlùfáà àgbà tí ó tóbi nínú Jésù tí ó ní òye àwọn ìdanwò wa - tí a ti dán wò bíi àwa ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ - tí ó sì ti kọjá ní ọ̀run. Àlùfáà Àgbà wa ti lọ sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run gan-an, ó "lọ sí ẹ̀yìn aṣọ ìkélé" gẹ́gẹ́ bí "ìdákọ̀ró ọkàn wa" (Héb. 6:19). Ìdí nìyẹn tí a fi ní ìgboyà láti "sún mọ́ ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́" (Héb. 4:16). 

Ìgboyà wa kò sinmi lórí bí a ṣe mọ àdúrà gbà tó. Kì í ṣe torí pé a jẹ́ ọ̀jáfáfá tàbí pé a ní òye, tàbí pé a jẹ́ ènìyàn dáadáa. A lè sún mọ́ Baba nítorí ohun tí Jésù ṣe fún wa. Ìdí tí èyí fi jẹ́ ìròyìn rere ni pé a lè wá ní mímọ́ níwájú Ọlọ́run nítorí pé ìwà rere wa, òye wa tàbí ìfọkànsìn wa kò lè dé iwájú Ọlọ́run. Kristi ti ṣe ohun gbogbo fún wa. Kristi gbà wá là, kì í ṣe nínú ìwà rere wa, ṣùgbọ́n nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa Ó kú fún wa (Róòmù 5:8). 

Nítorí náà, ní ìgbà tí ẹ bá ń gba àdúrà, ẹ ronú nípa ohun tí ẹ ń ṣe ní ìgbà tí ẹ bá ní ìrírí àìsẹ dáadá yín ní ibi àdúrà. Ṣé o máa ń rẹ̀wẹ̀sì, kí o wá máa ṣe ìlérí fún Ọlọ́run pé wàá túbọ̀ sapá, tàbí kí o máa sapá láti ṣe dáadáa ju bí o ṣe rí lọ, kí o sì gbìyànjú ṣùgbọ́n kí o tún ṣì kùnà? Ǹjẹ́ o máa ń tijú láti gba àdúrà nítorí pé o kò lè sinmi nínú òtítọ́ náà pé Ọlọ́run mọ̀ pé o kò mọ bí o ṣe lè gba àdúrà? Báwo ni àdúrà rẹ ṣe lè yí padà bí o bá gbé àwọn àṣìṣe rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nínú àdúrà, tí o wá Ọlọ́run tí ó mọ̀ pé o kò mọ bí o ṣe ń gba àdúrà tí ó sì ti fi ọ̀nà àbáyọ fún ọ?

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Where Prayer Becomes Real

Àdúrà ní ìgbà míràn lè dà bíi ẹni wípé o dá nìkan wà. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, nínú àdúrà, mo gbìyànjú láti mú ẹ̀mí àti ọkàn mi dákẹ́, èrò inú mi sì ń sáré káàkiri. Ní ìgbà míràn mo kàn ma sùn lọ. Àwọn ìgbà kan wà tí ó dà bíi wípé àdúrà mi máa ń ta ba òrùlé padà. Àmọ́ ohun tí a kìí sábà mọ̀ ni wípé Olúwa n fún wa ní ìròyìn rere ní àwọn ibi wọ̀nyí. Ẹ jẹ́ kí á lo àkókò díẹ̀ láti gbé ìhìn rere nípa àdúrà yẹ̀ wò.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ilé-iṣẹ́ Ìtẹ̀wé Baker fún ìpèsè ètò yí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://bakerbookhouse.com/products/235866