Ìgbésí Ayé Tí Ó Fi Ìdí M'úlẹ̀Àpẹrẹ

“ Wíwa ninu Iṣẹ Apínfúnni”
Ìwé-mímọ: Matiu 28:16-20; Ìṣe 1:8; 2 Kọrinti 5:11-21
Ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jùlọ láti na ọwọ mú kí ayé le di ti Krísti sinmi lórí irú ènìyàn ti a fẹ́ da. Bí a ṣe wà ni dídára-tó òhún ni iṣẹ-àpinfúnni wa. Ìròyìn dídùn náà ni wípé Jésù kò retí ki á di ẹni pípé kí O tó pè wá láti wá ṣe iṣẹ́ àpinfúnni. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, jíjẹ́ “pípé” kò ka wá yẹ láti lè bá Jésù pin nínú iṣẹ́ àpinfúnni.
Nígbàtí o bá ka Bíbélì, iwọ yíò ríi léraléra wípé Ọlọ́run kìí pe àwọn èniyàn ti ó pé pérépéré. Iṣẹ́ Ọlọ́run ni láti máa pe àwọn onirẹwẹsi, tí m'bẹrù, ònínufùfù, aláiṣedéde, aláinìrètí, tí nṣiyèmeji ènìyàn bí iwọ àti èmi. Wo àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀.
Bí a ti mú Jésù tí a sì kàn a mọ àgbélébùú, àwọn ọmọlẹ̀hìn Rẹ sá fún. A fi í sílẹ̀ láti jìyà kó sì kú. Lẹ́hìn ikú Rẹ̀, ìsìnkú, àti àjíǹde, àwọn ọmọlẹ̀hìn ti ara wọ́n pamọ́ sínú iyàrá kan nítorí ibẹ̀rù wípé àwọn náà lè kú. Àwọn ọmọlẹ̀hìn wọ̀nyí ti já Jésù kulẹ̀. Wọ́n ti kúrò. Ta ní yió fẹ́ irú àwọn èniyàn báwọ̀nyí nínú ẹgbẹ́ òun? Ìdáhùn náà ni wípé kò sẹ́ni àyàfi Jésù.
Jésù padà lọ bá àwọn ọmọlẹ̀hìn Rẹ̀ tí wọ́n kùnà, dépò kí O máa sọ àṣìṣe wọn, níṣe ni Ó rán wọ́n ni iṣẹ́ àpinfúnni. Lẹ́hìn tó bá àwọn ọ̀rẹ́ Rẹ̀ pàdé lójúkojú, ó sọ wípé, "Àlàáfíà kí ó wà pẹ̀lú yín. Gẹ́gẹ́ bí Bàbá ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi pẹ̀lú ń rán yín." Lẹ́hìn tí Ó ti sọ báyìí tán, "Ó mí èémí Rẹ̀ lé wọn lórí, ó sì wí fún wọn wípé, 'ẹ gba ẹ̀mí mímọ́' " (Jòhánù 20:21–22).
Kódà nígbà tí o bá ṣe àṣìṣe, tí o kò ṣe ohun tí ó yẹ, tí o kò le ko ará rẹ jọ, Jésù wá sọ́dọ̀ rẹ Ó sì wípé, "Mo fẹ́ ọ. Mo ńpè ọ́, Mo sì ń rán ọ. Jésù mọ àwọn ìṣòro rẹ, àwọn ohun tió ti di bárakú fún ọ, àwọn ìdoríkodo rẹ, àti àwọn ìkùnà rẹ, síbẹ̀, a pè ọ sínú iṣẹ́ àpinfúnni tí òun rán ọ.
Àwọn nǹkan wo ni àwọn ènìyàn tó sún mọ́ ọ jùlọ nílò? Báwo ní o ṣe lè máa hùwà bíi Kristi sí wọn nínú irú ipò bẹ́ẹ̀?
A n'ireti wípé Ètò yìí gba ọ níyànjú. Kọ ẹ̀kọ díẹ si nihìn .
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Gẹ́gẹ́ bí Pásítọ̀ New York Rich Villodas ṣe ṣàlàyé rẹ̀, ìgbésí ayé tí o dagba nipa ti emi gidi gan-an, jẹ́ ìgbésí ayé tí ó mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpele ìṣọ̀kan ẹ̀mí papọ̀, nipa airekọjá, ìṣẹ́gun, àti ṣíṣe aṣọpọ awon ohun ti ẹmi. Irúfẹ́ ìgbésí ayé yìí pè wá láti jẹ́ àwọn ènìyàn ti ìgbésí ayé pẹ̀lú Ọlọ́run nínú àdúrà ti mo lara, to n sise ilaja, to n ṣiṣẹ́ òdodo, to wa ni alaafia pelu Olorun nipa ti ẹni ti inu, kí wọ́n sì rí ara àti ìbálòpọ̀ wọ́ń gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fun iṣẹ́ iriju.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí https://www.richvillodas.com/