Ìgbésí Ayé Tí Ó Fi Ìdí M'úlẹ̀Àpẹrẹ

“Ìbálòpọ̀ Tó Pé Pérépéré”
Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni ìtàn ẹ̀dá ènìyàn ti jẹ́ ti rògbòdìyàn àti àjèjì pẹ̀lú ara wa.
Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ni párádísè tí a ṣe ìpèse rẹ̀ ní kíkún, Ó sì fi ààlà pàtàkì kan lélẹ̀: wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti búburú. Láìpẹ́ jọjọ, ejò kan yọjú, o si ṣe ẹ̀tànjẹ tọkọtaya náà láti jẹ lára igi yìí. Báyìí a ka ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣẹ tí o burú jùlọ nínu Bíbélì: "Ojú àwọn méjèèjì si là, nwọn si mọ̀ wípé nwọn wà ni ìhoho; nwọn si gán ewé ọ̀pọtọ pọ̀, nwọn si dá ibantẹ fún ara wọn" (Jẹ́nẹ́sísi 3:7).
Ẹ̀ṣẹ̀ ló sọ ojú wọn dìdàkudà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ la ojú wọn. Ṣáájú àkókò yìí, ojú mímọ ti Ọlọ́run ni wọ́n fi ń ríran. Wàyí o, wọ́n wá rí ìran tí kò dára nípa bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ṣubú.
Àwọn àbájáde rẹ̀ yíò máa dààmú ẹ̀dá ènìyàn lọ síwájú. Síbẹ̀ lónìí, bí a bá ń ronú ara wa àti ìbálòpọ̀, a máa ń ṣe é pẹ̀lú ẹrù ìtìjú, àbámọ̀, ìbànújẹ́, àti ìbínú.
Ṣùgbọ́n èyí kìí ṣe òpin ìtàn wa. Ìrètí ṣì wà. Nípasẹ̀ agbára àti ìfẹ́, Ọlọ́run lè da wá dáradára ní ọ̀nà Jésù. Nínú Rẹ̀, a ti borí ìdè wa. Àwọn ọgbẹ́ wa kọ́ lo ni ohùn ikẹhìn. Kristi ti ṣẹ́gun.
Nínu Jésù, a ṣe ìpèsè ẹdá ènìyàn túntún: ọkán ti kò si nínu ìgbèkùn túbú ẹ̀ṣẹ àti itiju ṣùgbọ́n ti o ní òmìnira nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti ìfẹ Ọlọ́run. Nípasẹ iwà àrà ọ̀tọ̀ eyi tí o kan igi yẹn nínú Ọgbà Ídẹ́nì yẹn, ló mú kí ẹ̀ṣẹ̀ di ohun tó burú jáì nínú ayé. Ṣùgbọ́n nigbanà ní Jésù wá àti wípé, nípa ìṣe'gbọ́ran, O yi ipá-ọ̀na àgbáyé padà láíláí.
Bẹ́ẹ̀ ni, Ádámù àti Éfà sá sẹ́hìn ìgi kan, ní ìhòòhò ìtìjú sì borí wọ́n. Ṣùgbọ́n Jésù gbé kọ́ lórí igi, ní ìhòòhò, ó sì borí ìtìjú.
Nínú Jésù, ìtìjú kò ni ọrọ ìkẹhìn lẹnu. Ko kán dandan ki àwọn ìfẹ inú wa wà láì léto. A lè máa gbé nínú òmìnira tí ó wá nnú orúkọ Rẹ̀.
Ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn ló máa ń jẹ́ kí éniyàn ní ìbálòpọ̀ tó pé pérépéré. Njẹ́ ìfẹ́ ìbálòpọ̀ rẹ ti dá ori rú bí? Wá ẹnìkán tàbí àwùjọ ìrànlọ́wọ́ kán. Njẹ́ o n dáwà bí? Máa bá àwọn ènìyàn kẹ́gbẹ́ pọ̀. Njẹ́ o ti ṣè igbéyàwó bí? Máa bá ọkọ tàbí aya rẹ sọ̀rọ̀ déédéé, èyí tó jẹ́ wípé kìkì ìbálòpọ̀ nìkan ló lè jẹ́ kó ṣeé ṣe.
Nípa Ìpèsè yìí

Gẹ́gẹ́ bí Pásítọ̀ New York Rich Villodas ṣe ṣàlàyé rẹ̀, ìgbésí ayé tí o dagba nipa ti emi gidi gan-an, jẹ́ ìgbésí ayé tí ó mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpele ìṣọ̀kan ẹ̀mí papọ̀, nipa airekọjá, ìṣẹ́gun, àti ṣíṣe aṣọpọ awon ohun ti ẹmi. Irúfẹ́ ìgbésí ayé yìí pè wá láti jẹ́ àwọn ènìyàn ti ìgbésí ayé pẹ̀lú Ọlọ́run nínú àdúrà ti mo lara, to n sise ilaja, to n ṣiṣẹ́ òdodo, to wa ni alaafia pelu Olorun nipa ti ẹni ti inu, kí wọ́n sì rí ara àti ìbálòpọ̀ wọ́ń gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fun iṣẹ́ iriju.
More
A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí https://www.richvillodas.com/