Ìgbésí Ayé Tí Ó Fi Ìdí M'úlẹ̀Àpẹrẹ

The Deeply Formed Life

Ọjọ́ 3 nínú 5

“Àyẹ̀wò Inú”

Àyẹwò inu jẹ ọna ìgbésí ayé ti o nṣe àgbéyẹ̀wò ootọ́ ijìnlẹ ìgbé ayé wa, láti ṣe áaye fún ìdàgbàsókè tiwá àti ìpe na làti nìfẹ dáradára.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbésí ayé òde òní ni kò fara mọ́ irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀. Púpọ àwọn ọjọ́ wa ni o ti gbèro láì kíyèsara láti kọ ẹ̀hìn si àti máa wo ohun ti ó wà lábẹ́lẹ̀. A sábà máa ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ ìjọsìn tó ńfẹ́ iná àinirojinlẹ̀. A lo Ọlọ́run láti sá fún Ọlọ́run, a sì fi Ọlọ́run sá fún ara wa.

Nínú Orin Dáfídì 139, a rí okàn-àyà ẹnì kan tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ fún ṣíṣe àyẹ̀wò inú to péye: Dáfídì. Àwọn ẹsẹ̀ mẹ́rìnlá àkọ́kọ́ nínú iwe Orin Dáfídì náà dá lórí ìmọ̀ tí Ọlọ́run ní nípa ìran ènìyàn àti Dáfídì ní pàtàkì. Ṣùgbọ́n ni ọwọ́ ìparí Orin Dáfídì náà, oó níran wípé Dáfídì mọ̀ dajú wípé bi Ọlọ́run tí mọ gbogbo nǹkan nípa òun tó, Dáfídì ò mọ gbogbo nǹkan nípa ara rẹ̀. Nítorí náà, nínú ọ̀rọ̀ tí ó jẹ mọ́ ìmọrírì àti ìjẹ́wọ́, ó kọ̀wé,

Wádìí mi, Ọlọ́run, kí O si mọ ọkàn mi!

Dán mi wò kí O si mọ èrò ọkàn mi!

Kí O sì wò bí ipá ọnà búburú kàn bá wà nínú mi.

Kí O sì fi ese mi lé ònà àìnípẹkun!(orí 23 - 24)

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa ló fẹ́ mọ Ọlọ́run. Ṣugbọ́n ohun ti a tún nílò ni kí á mọ irú ènìyàn ti a jẹ́. Dáfídì fi ìdí rẹ̀ múlẹ wípé Ọlọ́run mọ gbogbo ǹkan, nítorína ó béèrè fún ìṣípayá, kì í ṣe ti Ọlọ́run, bí kò ṣe ti ara rẹ̀. Ohun ti ó wà lọ́kàn Dáfídì ni láti lọ lábẹ́lẹ̀.

Ní àbábọ ìwé olúfọkànsìn yí, mo ti ṣe ohùn-rará pàtàkìí àti máa tẹ́ti. Ọnà àgbéyẹ̀wò pẹlú ni kí a tẹ́ti ìgbọràn gidi sí Ọlọ́run. Ọnà àti korajọpọ̀ ni kí a ṣe ìgbọràn láarin ará wa. Ọnà àti ṣé àyẹwò inú to péye jẹ làti máa tẹ́ti sí ara wa.

Nígbàtí a bá ṣe àṣerò àwọn Orin Dáfídì àti àwọn ẹ̀sẹ̀ Bíbélì mìíràn fún àyẹ̀wò inú, aó bẹ̀rẹ̀ síí rí pàtàkì tí wọ́n fún ìṣe aṣarò àti kíkópa ayé ti inú. Ṣùgbọ́n ó gba iṣẹ́ díẹ̀. Dáfídì, nínu ìwé Orin Dáfídì, ṣe òhun mẹ́ta kàn yanju èyí tí a pè wá láti tẹ̀le. Ó wá àyè láti yẹ inú ara rẹ̀ wò, ó sì ní ìṣọ̀kan tó láti fi ayé rẹ̀ lélẹ̀ fún Ọlọ́run, ó sì ní ìgboyà láti dojú kọ ara rẹ̀. Àwa náà ńkọ́?

Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ: Lónìí, kí ló ń bí mi nínú? Tí n bà mi nínu jẹ́? Tí n gbé mi l'ọkan s'oke? Tó jẹ́ ìdùnnú mi? Jẹ́ kí àwọn òye wọnyí sún ọ sí adura.

Nípa Ìpèsè yìí

The Deeply Formed Life

Gẹ́gẹ́ bí Pásítọ̀ New York Rich Villodas ṣe ṣàlàyé rẹ̀, ìgbésí ayé tí o dagba nipa ti emi gidi gan-an, jẹ́ ìgbésí ayé tí ó mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpele ìṣọ̀kan ẹ̀mí papọ̀, nipa airekọjá, ìṣẹ́gun, àti ṣíṣe aṣọpọ awon ohun ti ẹmi. Irúfẹ́ ìgbésí ayé yìí pè wá láti jẹ́ àwọn ènìyàn ti ìgbésí ayé pẹ̀lú Ọlọ́run nínú àdúrà ti mo lara, to n sise ilaja, to n ṣiṣẹ́ òdodo, to wa ni alaafia pelu Olorun nipa ti ẹni ti inu, kí wọ́n sì rí ara àti ìbálòpọ̀ wọ́ń gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fun iṣẹ́ iriju.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ WaterBrook Multnomah fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí https://www.richvillodas.com/