O. Daf 88:13-15
O. Daf 88:13-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn iwọ ni mo kigbe si, Oluwa; ati ni kutukutu owurọ li adura mi yio ṣaju rẹ. Oluwa, ẽṣe ti iwọ fi ṣa ọkàn mi tì? ẽṣe ti iwọ fi pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi? Iṣẹ́ nṣẹ mi, emi mura ati kú lati igba ewe mi wá: nigbati ẹ̀ru rẹ ba mbà mi, emi di gbéregbère.
Pín
Kà O. Daf 88O. Daf 88:13-15 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn OLUWA, èmi ń ké pè ọ́; ní òwúrọ̀ n óo gbadura sí ọ. OLUWA, kí ló dé tí o fi ta mí nù? Kí ló dé tí o fi ojú pamọ́ fún mi? Láti ìgbà èwe mi ni a tí ń jẹ mí níyà, tí mo sì fẹ́rẹ̀ kú, mo ti rí ìjẹníyà rẹ tí ó bani lẹ́rù; agara sì ti dá mi.
Pín
Kà O. Daf 88O. Daf 88:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, OLúWA; ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ. OLúWA, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi? Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi, èmi múra àti kú; nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí, èmi di gbére-gbère
Pín
Kà O. Daf 88