Saamu 88:13-15

Saamu 88:13-15 YCB

Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, OLúWA; ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ. OLúWA, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi? Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi, èmi múra àti kú; nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí, èmi di gbére-gbère