ORIN DAFIDI 88:13-15

ORIN DAFIDI 88:13-15 YCE

Ṣugbọn OLUWA, èmi ń ké pè ọ́; ní òwúrọ̀ n óo gbadura sí ọ. OLUWA, kí ló dé tí o fi ta mí nù? Kí ló dé tí o fi ojú pamọ́ fún mi? Láti ìgbà èwe mi ni a tí ń jẹ mí níyà, tí mo sì fẹ́rẹ̀ kú, mo ti rí ìjẹníyà rẹ tí ó bani lẹ́rù; agara sì ti dá mi.