O. Daf 88:13-15

O. Daf 88:13-15 YBCV

Ṣugbọn iwọ ni mo kigbe si, Oluwa; ati ni kutukutu owurọ li adura mi yio ṣaju rẹ. Oluwa, ẽṣe ti iwọ fi ṣa ọkàn mi tì? ẽṣe ti iwọ fi pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi? Iṣẹ́ nṣẹ mi, emi mura ati kú lati igba ewe mi wá: nigbati ẹ̀ru rẹ ba mbà mi, emi di gbéregbère.