Sekariah 8:1-3

Sekariah 8:1-3 YCB

Ọ̀rọ̀ OLúWA àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá. Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Owú ńláńlá ni mo jẹ fún Sioni, pẹ̀lú ìbínú ńláńlá ni mo fi jowú fún un.” Báyìí ni OLúWA wí: “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu: Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá OLúWA àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.”