Sek 8:1-3
Sek 8:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Oluwa awọn ọmọ-ogun si tun tọ̀ mi wá, wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; owu nlanla ni mo jẹ fun Sioni, ikannu nlanla ni mo fi jowu fun u. Bayi li Oluwa wi; Mo ti yipada si Sioni emi o si gbe ãrin Jerusalemu: a o si pè Jerusalemu ni ilu nla otitọ; ati oke nla Oluwa awọn ọmọ-ogun, okenla mimọ́ nì.
Sek 8:1-3 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA àwọn ọmọ ogun tún bá mi sọ̀rọ̀ pé Òun fẹ́ràn àwọn ará Sioni; nítorí náà ni inú òun ṣe ru sí àwọn ọ̀tá wọn. Ó ní, òun óo pada sí Sioni, òun óo máa gbé Jerusalẹmu, a óo máa pe Jerusalẹmu ní ìlú olóòótọ́, òkè OLUWA àwọn ọmọ ogun, ati òkè mímọ́.
Sek 8:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀ OLúWA àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá. Báyìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Owú ńláńlá ni mo jẹ fún Sioni, pẹ̀lú ìbínú ńláńlá ni mo fi jowú fún un.” Báyìí ni OLúWA wí: “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu: Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá OLúWA àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.”