Sek 8:1-3

Sek 8:1-3 YBCV

Ọ̀RỌ Oluwa awọn ọmọ-ogun si tun tọ̀ mi wá, wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; owu nlanla ni mo jẹ fun Sioni, ikannu nlanla ni mo fi jowu fun u. Bayi li Oluwa wi; Mo ti yipada si Sioni emi o si gbe ãrin Jerusalemu: a o si pè Jerusalemu ni ilu nla otitọ; ati oke nla Oluwa awọn ọmọ-ogun, okenla mimọ́ nì.