Jobu 34:1-9

Jobu 34:1-9 BMYO

Nígbà náà ni Elihu dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ẹ sì fi etí sílẹ̀ sí mi ẹ̀yin tí ẹ ní ìmòye. Nítorí pé etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò, bí adùn ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò. Ẹ jẹ́ kí a mọ òye ohun tí o tọ́ fún ara wa; ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrín wa. “Nítorí pé Jobu wí pé, ‘Aláìlẹ́ṣẹ̀ ni èmi; Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ. Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí, bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi, ọfà rẹ̀ kò ní àwòtán ọgbẹ́.’ Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jobu, tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi? Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó sì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn. Nítorí ó sá ti wí pé, ‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn, tí yóò fi máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’