Job 34:1-9
Job 34:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
PẸLUPẸLU Elihu dahùn o si wipe, Ẹnyin ọlọgbọ́n, ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi, ki ẹ si dẹtisilẹ si mi, ẹnyin ti ẹ ni ìmoye. Nitoripe eti a ma dán ọ̀rọ wò, bi adùn ẹnu ti itọ onjẹ wò. Ẹ jẹ ki a ṣà idajọ yàn fun ara wa; ẹ jẹ ki a mọ̀ ohun ti o dara larin wa. Nitoripe Jobu wipe, Olododo li emi; Ọlọrun si ti gbà idajọ mi lọ. Emi ha lè ipurọ si itọsí mi bi, ọfa mi kò ni awọtan, laiṣẹ ni. Ọkunrin wo li o dabi Jobu, ti nmu ẹ̀gan bi ẹni mu omi. Ti mba awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ kẹgbẹ, ti o si mba awọn enia buburu rin. Nitori o sa ti wipe, Ère kan kò si fun enia, ti yio fi ma ṣe inu didun si Ọlọrun
Job 34:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Elihu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní, “Ẹ gbọ́rọ̀ mi, ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n, ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ ní ìmọ̀, nítorí bí ahọ́n ti í máa ń tọ́ oúnjẹ wò, bẹ́ẹ̀ ni etí náà lè máa tọ́ ọ̀rọ̀ wò Ẹ jẹ́ kí á yan ohun tí ó tọ́, kí á jọ jíròrò ohun tí ó dára láàrin ara wa. Jobu sọ pé òun kò jẹ̀bi, ó ní Ọlọrun ni ó kọ̀ tí kò dá òun láre. Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun jàre, Ọlọrun ka òun kún òpùrọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò dẹ́ṣẹ̀, ọgbẹ́ òun kò ṣe é wòsàn. “Ta ló dàbí Jobu, tí ń kẹ́gàn Ọlọrun nígbà gbogbo, tí ó ń bá àwọn aṣebi kẹ́gbẹ́, tí ó sì ń bá àwọn eniyan burúkú rìn? Nítorí ó ń sọ pé, ‘Kò sí èrè kankan, ninu ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọrun.’
Job 34:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Nígbà náà ni Elihu dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ẹ sì fi etí sílẹ̀ sí mi ẹ̀yin tí ẹ ní ìmòye. Nítorí pé etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò, bí adùn ẹnu ti ń tọ́ oúnjẹ wò. Ẹ jẹ́ kí a mọ òye ohun tí o tọ́ fún ara wa; ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàrín wa. “Nítorí pé Jobu wí pé, ‘Aláìlẹ́ṣẹ̀ ni èmi; Ọlọ́run sì ti gba ìdájọ́ mi lọ. Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí, bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi, ọfà rẹ̀ kò ní àwòtán ọgbẹ́.’ Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jobu, tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi? Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó sì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn. Nítorí ó sá ti wí pé, ‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn, tí yóò fi máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’