O. Daf 132:3-5

O. Daf 132:3-5 YBCV

Nitõtọ, emi kì yio wọ̀ inu agọ ile mi lọ, bẹ̃li emi kì yio gùn ori akete mi; Emi kì yio fi orun fun oju mi, tabi õgbe fun ipenpeju mi, Titi emi o fi ri ibi fun Oluwa, ibujoko fun Alagbara Jakobu.